Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 11:4-16 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ẹ ranti ohun tí ó ṣe sí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Ijipti ati sí àwọn ẹṣin wọn ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn; bí ó ti jẹ́ kí omi Òkun Pupa bò wọ́n mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n ń le yín bọ̀, ati bí OLUWA ti pa wọ́n run títí di òní olónìí.

5. Ẹ ranti ohun gbogbo tí ó ṣe fun yín ninu aṣálẹ̀ títí tí ẹ fi dé ìhín;

6. ati ohun tí ó ṣe sí Datani ati Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ọmọ ọmọ Reubẹni. Ẹ ranti bí ilẹ̀ ti lanu, tí ó sì gbé wọn mì ati àwọn ati gbogbo ìdílé wọn, ati àgọ́ wọn, ati gbogbo iranṣẹ ati ẹran ọ̀sìn wọn, láàrin gbogbo Israẹli.

7. Ẹ ti fi ojú rí gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí OLUWA ṣe.

8. “Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́ kí ẹ lè ní agbára tó láti gba ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá lọ láti gbà.

9. Kí ẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA ti búra fún àwọn baba yín pé òun yóo fún wọn ati àwọn arọmọdọmọ wọn. Ilẹ̀ tí ó lọ́ràá tí ó sì ní ẹ̀tù lójú tí ó kún fún wàrà ati oyin.

10. Nítorí pé, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà yìí, kò rí bí ilẹ̀ Ijipti níbi tí ẹ ti jáde wá; níbi tí ó jẹ́ pé nígbà tí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn yín tán, ẹ óo ṣe wahala láti bu omi rin ín, bí ìgbà tí à ń bu omi sí ọgbà ẹ̀fọ́.

11. Ṣugbọn ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà yìí jẹ́ ilẹ̀ tí ó kún fún òkè ati àfonífojì. Láti ojú ọ̀run ni òjò ti ń rọ̀ sí i.

12. OLUWA Ọlọrun yín tìkararẹ̀ ni ó ń tọ́jú rẹ̀, tí ó sì ń mójútó o láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún títí dé òpin.

13. “Tí ẹ bá tẹ̀lé òfin mi tí mo fun yín lónìí, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì sìn ín pẹlu gbogbo ọkàn ati ẹ̀mí yín,

14. yóo rọ òjò sórí ilẹ̀ yín ní àkókò rẹ̀, ati òjò àkọ́rọ̀ ati ti àrọ̀kẹ́yìn, kí ẹ baà lè kórè ọkà, ọtí waini, ati òróró olifi yín.

15. Yóo mú kí koríko dàgbà ninu pápá fún àwọn ẹran ọ̀sìn yín, ẹ óo jẹ, ẹ óo sì yó.

16. Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ̀tàn má baà wọ inú ọkàn yín, kí ẹ má baà yipada sí àwọn oriṣa, kí ẹ sì máa bọ wọ́n.

Ka pipe ipin Diutaronomi 11