Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Daniẹli 6:13-23 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Wọ́n bá sọ fún ọba pé, “Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ìgbèkùn Juda kò kà ọ́ sí, kò sì pa òfin rẹ mọ́. Ṣugbọn ìgbà mẹta lóòjọ́ níí máa gbadura.”

14. Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ọkàn rẹ̀ dàrú lọpọlọpọ, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ títí ilẹ̀ fi ṣú láti gba Daniẹli sílẹ̀.

15. Àwọn ọkunrin wọnyi gbìmọ̀, wọ́n sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, o mọ̀ pé òfin Mede ati ti Pasia ni pé òfin tí ọba bá ṣe kò gbọdọ̀ yipada.”

16. Ọba bá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Daniẹli, kí wọ́n sì jù ú sinu ihò kinniun. Ṣugbọn ó sọ fún Daniẹli pé, “Ọlọrun rẹ tí ò ń sìn láìsinmi yóo gbà ọ́.”

17. Wọ́n yí òkúta dí ẹnu ihò kinniun náà. Ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ sì fi òǹtẹ̀ òrùka wọn tẹ ọ̀dà tí wọ́n yọ́ lé e, kí ẹnikẹ́ni má lè gba Daniẹli sílẹ̀.

18. Ọba bá lọ sí ààfin rẹ̀, ó fi gbogbo òru náà gbààwẹ̀. Kò jẹ́ kí àwọn eléré ṣe eré níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì lè sùn.

19. Bí ilẹ̀ ti mọ́, ọba dìde, ó sáré lọ sí ibi ihò kinniun náà.

20. Nígbà tí ó dé ẹ̀bá ibẹ̀, ó kígbe pẹlu ohùn arò, ó ní, “Daniẹli, iranṣẹ Ọlọrun Alààyè, ǹjẹ́ Ọlọrun tí ò ń sìn láìsinmi gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn kinniun?”

21. Daniẹli dáhùn pé, “Kabiyesi, kí ọba pẹ́,

22. Ọlọrun mi ti rán angẹli rẹ̀, ó ti dí àwọn kinniun lẹ́nu, wọn kò sì pa mí lára. Nítorí pé n kò jẹ̀bi níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ṣe nǹkan burúkú sí ìwọ ọba.”

23. Inú ọba dùn pupọ, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n yọ Daniẹli jáde. Wọ́n bá yọ Daniẹli jáde kúrò ninu ihò kinniun, àwọn kinniun kò sì pa á lára rárá, nítorí pé ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun rẹ̀.

Ka pipe ipin Daniẹli 6