Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Daniẹli 11:3-18 BIBELI MIMỌ (BM)

3. “Ọba olókìkí kan yóo wá gorí oyè, pẹlu ipá ni yóo máa fi ṣe ìjọba tirẹ̀, yóo sì máa ṣe bí ó bá ti wù ú.

4. Lẹ́yìn tí ó bá jọba, ìjọba rẹ̀ yóo pín sí ọ̀nà mẹrin. Àwọn ọba tí yóo jẹ lẹ́yìn rẹ̀ kò ní jẹ́ láti inú ìran rẹ̀, kò sì ní sí èyí tí yóo ní agbára tó o ninu wọn; nítorí a óo gba ìjọba rẹ̀, a óo sì fún àwọn ẹlòmíràn.

5. “Ọba Ijipti ní ìhà gúsù yóo lágbára, ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo lágbára jù ú lọ, ìjọba rẹ̀ yóo sì tóbi ju ti ọba lọ.

6. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ọba Ijipti yóo ní àjọṣepọ̀ pẹlu ọba Siria, ní ìhà àríwá, ọmọbinrin ọba Ijipti yóo wá sí ọ̀dọ̀ ọba Siria láti bá a dá majẹmu alaafia; ṣugbọn agbára ọmọbinrin náà yóo dínkù, ọba pàápàá ati ọmọ rẹ̀ kò sì ní tọ́jọ́. A óo kọ obinrin náà sílẹ̀, òun ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀, ati alátìlẹ́yìn rẹ̀.

7. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ yóo jọba ní ipò rẹ̀, yóo wá pẹlu ogun, yóo wọ ìlú olódi ọba Siria, yóo bá wọn jagun, yóo sì ṣẹgun wọn.

8. Yóo kó àwọn oriṣa wọn, ati àwọn ère wọn lọ sí ilẹ̀ Ijipti, pẹlu àwọn ohun èlò olówó iyebíye wọn tí wọ́n fi wúrà ati fadaka ṣe; kò sì ní bá ọba Siria jagun mọ́ fún ọdún bíi mélòó kan.

9. Ọba Siria yóo wá gbógun ti ọba Ijipti, ṣugbọn yóo sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀.

10. “Àwọn ọmọ ọba Siria yóo gbá ogun ńlá jọ, wọn yóo sì kó ogun wọn wá, wọn yóo jà títí wọn yóo fi wọ ìlú olódi ti ọ̀tá wọn.

11. Inú yóo bí ọba Ijipti, yóo sì lọ bá ọba Siria jagun. Ọba Siria yóo kó ọpọlọpọ ogun jọ, ṣugbọn Ijipti yóo ṣẹgun rẹ̀.

12. Ọba Ijipti óo máa gbéraga nítorí ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí ọpọlọpọ ogun yìí, yóo sì pa ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun, ṣugbọn kò ní borí.

13. “Nítorí pé ọba Siria yóo tún pada lọ, yóo kó ogun jọ, tí yóo pọ̀ ju ti iṣaaju lọ. Nígbà tí ó bá yá, lẹ́yìn ọpọlọpọ ọdún, yóo pada wá pẹlu ikọ̀ ọmọ ogun tí ó lágbára, pẹlu ọpọlọpọ ihamọra ati ohun ìjà.

14. Ní àkókò náà, ọ̀pọ̀ eniyan yóo dìde sí ọba Ijipti; àwọn oníjàgídíjàgan láàrin àwọn eniyan rẹ̀ yóo dìde kí ìran yìí lè ṣẹ; ṣugbọn wọn kò ní borí.

15. Ọba Siria yóo wá dóti ìlú olódi kan, yóo sì gbà á. Àwọn ọmọ ogun Ijipti kò ní lágbára láti dojú ìjà kọ ọ́, àwọn akikanju wọn pàápàá kò ní lágbára mọ́ láti jagun.

16. Ọba Siria yóo ṣe wọ́n bí ó ti fẹ́ láìsí àtakò, yóo dúró ní Ilẹ̀ Dáradára náà, gbogbo rẹ̀ yóo sì wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.

17. “Ọba Siria yóo múra láti wá pẹlu gbogbo agbára ìjọba rẹ̀, yóo bá ọba Ijipti dá majẹmu alaafia, yóo sì mú majẹmu náà ṣẹ. Yóo fi ọmọbinrin rẹ̀ fún ọba Ijipti ní aya, kí ó lè ṣẹgun ọba Ijipti. Ṣugbọn yóo kùnà ninu ète rẹ̀.

18. Lẹ́yìn náà, yóo bá àwọn orílẹ̀-èdè ati àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní etíkun jà, yóo sì ṣẹgun ọpọlọpọ wọn. Ṣugbọn olórí-ogun kan yóo ṣẹgun rẹ̀, yóo sì pa òun náà run.

Ka pipe ipin Daniẹli 11