Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 18:2-18 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkandinlọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Abi, ọmọ Sakaraya.

3. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, nítorí pé ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ Dafidi, baba ńlá rẹ̀.

4. Ó wó gbogbo àwọn pẹpẹ oriṣa, ó wó gbogbo àwọn òpó tí wọ́n fi òkúta ṣe, ó sì gé gbogbo àwọn ère oriṣa Aṣera. Ó rún ejò idẹ tí Mose ṣe, tí wọn ń pè ní Nehuṣitani nítorí pé títí di àkókò náà àwọn ọmọ Israẹli a máa sun turari sí i.

5. Hesekaya ní igbagbọ ninu OLUWA Ọlọrun Israẹli. Juda kò sì ní ọba mìíràn tí ó dà bíi rẹ̀, yálà ṣáájú rẹ̀ ni, tabi lẹ́yìn rẹ̀.

6. Ó jẹ́ olóòótọ́ sí OLUWA, kò yapa kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣugbọn ó fi tọkàntọkàn pa àwọn òfin tí OLUWA fún Mose mọ́.

7. OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ó sì ń ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí ó ń ṣe. Ó gba ara rẹ̀ lọ́wọ́ ọba Asiria, ó di òmìnira, ó kọ̀ kò sìn ín mọ́.

8. Ó ṣẹgun àwọn ará Filistia, títí dé ìlú Gasa ati agbègbè tí ó yí i ká, ati ilé ìṣọ́ wọn, ati ìlú olódi wọn.

9. Ní ọdún kẹrin tíí Hesekaya jọba, tíi ṣe ọdún keje tí Hoṣea, ọmọ Ela, jọba lórí Israẹli, Ṣalimaneseri, ọba Asiria, gbógun ti Samaria, ó sì dó tì í.

10. Nígbà tí ó ti di ọdún kẹta tí ó ti dó ti Samaria, ó ṣẹgun rẹ̀. Èyí jẹ́ ọdún kẹfa tí Hesekaya jọba, ati ọdún kẹsan-an tí Hoṣea jọba.

11. Ọba Asiria kó àwọn ọmọ Israẹli ní ìgbèkùn lọ sí Asiria, ó sì kó wọn sí ìlú Hala ati Habori tí ó wà ní agbègbè odò Gosani ati sí àwọn ìlú àwọn ará Media.

12. Ogun kó Samaria nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli kò pa òfin OLUWA Ọlọrun wọn mọ́, wọ́n si da majẹmu tí OLUWA bá wọn dá. Wọn kò pa àwọn òfin tí OLUWA fún Mose, iranṣẹ rẹ̀ mọ́, wọn kò sì gbọ́ràn.

13. Ní ọdún kẹrinla tí Hesekaya jọba ní Juda, ni Senakeribu, ọba Asiria, gbógun ti àwọn ìlú olódi Juda, ó sì ṣẹgun wọn.

14. Hesekaya ranṣẹ sí Senakeribu, ọba Asiria, tí ó wà ní Lakiṣi nígbà náà, ó ní: “Mo ti ṣẹ̀, jọ̀wọ́ dá ọwọ́ ogun rẹ dúró; n óo sì san ohunkohun tí o bá bèèrè.” Ọba náà sì bèèrè fún ọọdunrun ìwọ̀n talẹnti fadaka ati ọgbọ̀n ìwọ̀n talẹnti wúrà lọ́wọ́ Hesekaya ọba Juda.

15. Hesekaya bá kó gbogbo fadaka tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ti inú ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin ranṣẹ sí i.

16. Ó sì ṣí wúrà tí ó wà lára ìlẹ̀kùn ilé OLUWA ati wúrà tí òun tìkararẹ̀ fi bo àwọn òpó ìlẹ̀kùn, ó kó wọn ranṣẹ sí Senakeribu.

17. Ọba Asiria rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀: Tatani, Rabusarisi ati Rabuṣake pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun láti Lakiṣi láti gbógun ti Hesekaya ní Jerusalẹmu. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu wọ́n dúró sí ibi ọ̀nà tí àwọn tí wọn ń hun aṣọ tí ń ṣiṣẹ́, lẹ́bàá kòtò omi tí ń ṣàn wá láti adágún omi tí ó wà ninu ìlú lápá òkè.

18. Nígbà tí wọ́n ké sí Hesekaya ọba, Eliakimu, ọmọ Hilikaya tí ó ń ṣe àkóso ààfin, ati Ṣebina akọ̀wé ọba, ati Joa ọmọ Asafu, tí ń ṣe àkóso ìwé ìrántí ni wọ́n jáde sí wọn.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 18