Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 17:1-18 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọdún kejila tí Ahasi jọba ní Juda, ni Hoṣea ọmọ Ela jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó sì jọba fún ọdún mẹsan-an.

2. Ó ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò tó ti àwọn ọba tí wọ́n jẹ ṣáájú rẹ̀.

3. Ṣalimaneseri Ọba Asiria gbógun tì í; Hoṣea bá jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún un, ó sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un ní ọdọọdún.

4. Ṣugbọn ní ọdún kan, Hoṣea ranṣẹ sí So, ọba Ijipti pé, kí ó ran òun lọ́wọ́, kò sì san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Asiria mọ́. Nígbà tí Ṣalimaneseri gbọ́, ó pàṣẹ pé kí wọ́n ju Hoṣea sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n.

5. Lẹ́yìn náà, Ṣalimaneseri, ọba Asiria, gbógun ti ilẹ̀ Israẹli, ó dó ti Samaria fún ọdún mẹta.

6. Ní ọdún kẹsan-an tí Hoṣea jọba, ọba Asiria ṣẹgun Samaria, ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli ní ìgbèkùn lọ sí Asiria. Ó kó wọn sí ìlú Hala ati sí etí odò Habori tí ó wà ní agbègbè Gosani, ati sí àwọn ìlú Media.

7. Ogun kó Samaria nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun wọn ó gbà wọ́n lọ́wọ́ ọba Farao, tí ó sì kó wọn jáde kúrò ní Ijipti. Wọ́n ti bọ oriṣa,

8. wọ́n sì tẹ̀lé ìwà àwọn eniyan tí OLUWA lé jáde kúrò fún wọn, ati àwọn àṣàkaṣà tí àwọn ọba Israẹli kó wá.

9. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe oríṣìíríṣìí nǹkan níkọ̀kọ̀, tí OLUWA Ọlọrun wọn kò fẹ́. Wọ́n kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ sinu àwọn ìlú wọn: wọ́n kọ́ sinu ilé ìṣọ́, títí kan àwọn ìlú olódi.

10. Wọ́n gbé àwọn òpó tí a fi òkúta ṣe ati àwọn ère Aṣerimu sí orí àwọn òkè ati sí abẹ́ àwọn igi tí wọ́n ní ìbòòji.

11. Wọ́n ń sun turari ní gbogbo orí òkè, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn tí OLUWA lé jáde kúrò ní ilẹ̀ náà. Wọ́n mú kí ibinu OLUWA ru pẹlu ìwà burúkú wọn,

12. wọ́n sì lòdì sí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn pé wọn kó gbọdọ̀ bọ oriṣa.

13. Sibẹ, OLUWA ń rán àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati àwọn wolii rẹ̀ kí wọ́n máa kìlọ̀ fún Israẹli ati Juda pé, “Ẹ kọ ọ̀nà burúkú yín sílẹ̀ kí ẹ sì pa òfin ati ìlànà mi, tí mo fún àwọn baba ńlá yín mọ́; àní àwọn tí mo fun yín nípasẹ̀ àwọn wolii, iranṣẹ mi.”

14. Ṣugbọn wọn kò gbọ́, wọ́n jẹ́ ọlọ́kàn líle bí àwọn baba ńlá wọn, tí wọn kò gba OLUWA Ọlọrun wọn gbọ́.

15. Wọ́n kọ ìlànà rẹ̀, wọn kò pa majẹmu tí ó bá àwọn baba ńlá wọn dá mọ́, wọn kò sì fetí sí àwọn ìkìlọ̀ rẹ̀. Wọ́n ń sin oriṣa lásánlàsàn, àwọn pàápàá sì di eniyan lásán. Wọ́n tẹ̀ sí ìwà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká; wọ́n kọ òfin tí OLUWA ṣe fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà wọn.

16. Wọ́n rú gbogbo òfin OLUWA Ọlọrun wọn; wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù meji, wọ́n ń sìn wọ́n. Wọ́n gbẹ́ ère oriṣa Aṣera, wọ́n sì ń bọ àwọn ohun tí ó wà lójú ọ̀run ati oriṣa Baali.

17. Wọ́n fi àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn rú ẹbọ sísun sí oriṣa, wọ́n ń ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn alásọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì fi ara wọn jì láti ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n sì fi bẹ́ẹ̀ rú ibinu rẹ̀ sókè.

18. Nítorí náà, OLUWA bínú sí àwọn ọmọ Israẹli, ó sì run wọ́n kúrò níwájú rẹ̀, ṣugbọn ó fi Juda nìkan sílẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 17