Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 16:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọdún kẹtadinlogun tí Peka, ọmọ Remalaya, jọba ní Israẹli, ni Ahasi, ọmọ Jotamu, jọba ní Juda.

2. Ẹni ogún ọdún ni Ahasi nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun. Kò tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere Dafidi baba ńlá rẹ̀, ṣugbọn ó ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀,

3. nípa títẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọba Israẹli. Òun náà tilẹ̀ fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun sí oriṣa gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè oníwà burúkú tí OLUWA lé kúrò lórí ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Israẹli.

4. Ní gbogbo ibi gíga, ati àwọn orí òkè ati abẹ́ gbogbo igi ni Ahasi tií máa rúbọ, tíí sìí sun turari.

5. Resini, ọba Siria, ati Peka, ọba Israẹli, gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n sì dó ti Ahasi, ṣugbọn wọn kò lè ṣẹgun rẹ̀.

6. Ní àkókò kan náà ni ọba Edomu gba Elati pada, ó sì lé àwọn ará Juda tí wọn ń gbé ibẹ̀, àwọn ará Edomu sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní olónìí.

7. Ahasi ranṣẹ lọ bá Tigilati Pileseri, ọba Asiria, ó ní, “Iranṣẹ ati ọmọ rẹ ni mo jẹ́, nítorí náà, jọ̀wọ́ wá gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọba Siria ati ti Israẹli tí wọ́n gbógun tì mí.”

8. Ahasi kó fadaka ati wúrà tí ó wà ninu ilé OLUWA, ati tinú àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin jọ, ó kó o ranṣẹ sí ọba Asiria.

9. Ọba Asiria gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó sì gbógun ti Damasku, ó ṣẹgun rẹ̀, ó pa Resini ọba, ó sì kó gbogbo àwọn eniyan ìlú náà lẹ́rú lọ sí Kiri.

10. Nígbà tí Ahasi lọ pàdé Tigilati Pileseri ọba, ní Damasku, ó rí pẹpẹ ìrúbọ kan níbẹ̀, ó sì ranṣẹ sí Uraya alufaa pé kí ó mọ irú rẹ̀ gan-an láìsí ìyàtọ̀ kankan.

11. Ki Ahasi tó dé, Uraya bá mọ irú pẹpẹ ìrúbọ náà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí Ahasi rán sí i láti Damasku.

12. Nígbà tí Ahasi pada dé, o rí i pé Uraya ti mọ pẹpẹ ìrúbọ náà; ó lọ sí ìdí rẹ̀,

13. ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ lórí rẹ̀. Ó rú ẹbọ ohun mímu, ó sì da ẹ̀jẹ̀ ẹbọ alaafia rẹ̀ sí ara rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 16