Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 11:2-8 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Joaṣi ọmọ Ahasaya nìkan ni kò pa nítorí pé Jehoṣeba ọmọbinrin Joramu ọba, arabinrin Ahasaya, gbé e sá lọ; ó sì fi òun ati alágbàtọ́ rẹ̀ pamọ́ sí yàrá kan ninu ilé OLUWA, kí Atalaya má baà pa á. Ó gbé e pamọ́ fún Atalaya, Atalaya kò sì rí i pa.

3. Joaṣi wà ní ìpamọ́ ninu ilé OLUWA fún ọdún mẹfa, Atalaya sì ń jọba lórí ilẹ̀ Juda.

4. Ṣugbọn ní ọdún keje, Jehoiada ranṣẹ pe àwọn olórí ogun tí wọn ń ṣọ́ ọba wá sí ilé OLUWA pẹlu àwọn olórí ogun tí wọn ń ṣọ́ ààfin. Ó bá wọn dá majẹmu, ó sì mú kí wọ́n búra láti fọwọsowọpọ pẹlu òun ninu ohun tí ó fẹ́ ṣe. Lẹ́yìn náà, ó fi ọmọ Ahasaya ọba hàn wọ́n.

5. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ìdámẹ́ta yín tí ó bá wá sí ibi iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi yóo máa ṣọ́ ààfin.

6. (Ìdámẹ́ta yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà Suri; ìdámẹ́ta yòókù yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà tí ó wà lẹ́yìn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin), wọn yóo dáàbò bo ààfin.

7. Àwọn ìpín mejeeji tí wọ́n bá ṣíwọ́ iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi, yóo wá dúró ní ilé OLUWA láti dáàbò bo ọba.

8. Wọn yóo dáàbò bo ọba pẹlu idà ní ọwọ́ wọn, wọn yóo sì máa bá a lọ sí ibikíbi tí ó bá ń lọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ wọn, pípa ni kí wọ́n pa á.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 11