Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 9:25-43 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Àwọn ará ìlú Ṣekemu bá rán àwọn kan ninu wọn, wọ́n lọ ba ní ibùba ní orí òkè de Abimeleki. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dá gbogbo àwọn tí wọn ń kọjá lọ́nà; ni ìròyìn bá kan Abimeleki.

26. Gaali ọmọ Ebedi ati àwọn arakunrin rẹ̀ kó lọ sí Ṣekemu, àwọn ará ìlú Ṣekemu sì gbẹ́kẹ̀lé e.

27. Àwọn ará ìlú Ṣekemu lọ sinu oko wọn, wọ́n ká èso àjàrà, wọ́n fi pọn ọtí fún wọn. Wọ́n jọ ń ṣe àríyá, wọ́n jọ lọ sí ilé oriṣa wọn, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi Abimeleki ṣe ẹlẹ́yà.

28. Gaali ọmọ Ebedi bá bèèrè pé, “Ta tilẹ̀ ni Abimeleki? Báwo sì ni àwa ará ìlú Ṣekemu ṣe jẹ́ sí i, tí a fi níláti máa sìn ín? Ṣebí àwọn ọmọ Hamori, baba Ṣekemu, ni Gideoni ati Sebulu, iranṣẹ rẹ̀ máa ń sìn? Kí ló dé tí àwa fi níláti máa sin Abimeleki?

29. Ìbá ṣe pé ìkáwọ́ mi ni àwọn eniyan yìí wà, ǹ bá yọ Abimeleki kúrò lórí oyè. Ǹ bá sọ fún Abimeleki pé kí ó lọ wá kún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kí ó jáde wá bá mi jà.”

30. Nígbà tí Sebulu, olórí ìlú náà gbọ́ ohun tí Gaali, ọmọ Ebedi wí, inú bí i gidigidi.

31. Ó ranṣẹ sí Abimeleki ní Aruma, ó ní, “Gaali, ọmọ Ebedi, ati àwọn arakunrin rẹ̀ ti dé sí Ṣekemu, wọn kò sì ní gbà fún ọ kí o wọ ibí mọ́.

32. Nítorí náà, tí ó bá di òru, kí ìwọ ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ lọ ba níbùba.

33. Bí ilẹ̀ bá ti mọ́, tí oòrùn sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ, gbéra, kí o sì gbógun ti ìlú náà. Nígbà tí Gaali ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá sì jáde sí ọ, mú wọn dáradára, kí o sì ṣe ẹ̀tọ́ fún wọn.”

34. Abimeleki ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá gbéra ní òru, wọ́n lọ ba níbùba lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ṣekemu, ní ìsọ̀rí mẹrin.

35. Gaali ọmọ Ebedi bá jáde, ó dúró ní ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà, Abimeleki ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ sì jáde níbi tí wọ́n ba sí.

36. Nígbà tí Gaali rí wọn, ó sọ fún Sebulu pé, “Wò ó, àwọn eniyan kan ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti orí òkè.”Sebulu dá a lóhùn pé, “Òjìji òkè ni ò ń wò tí o ṣebí eniyan ni.”

37. Gaali tún dáhùn, ó ní, “Tún wò ó, àwọn eniyan kan ń bọ̀ láti agbede meji ilẹ̀ náà, àwọn kan sì ń bọ̀ láti apá ibi igi Oaku àwọn tíí máa ń wo iṣẹ́.”

38. Ṣugbọn Sebulu dá a lóhùn, pé, “Gbogbo ẹnu tí ò ń fọ́n pin, tabi kò pin? Ṣebí ìwọ ni o wí pé, ‘Kí ni Abimeleki jẹ́ tí a fi ń sìn ín.’ Àwọn tí ò ń gàn ni wọ́n dé yìí, yára jáde kí o lọ gbógun tì wọ́n.”

39. Gaali bá kó àwọn ọkunrin Ṣekemu lẹ́yìn, wọ́n lọ gbógun ti Abimeleki.

40. Abimeleki lé Gaali, Gaali sì sá fún un, ọpọlọpọ eniyan fara gbọgbẹ́ títí dé ẹnu ibodè ìlú.

41. Abimeleki tún lọ ń gbé Aruma. Sebulu bá lé Gaali ati àwọn arakunrin rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú, kò sì jẹ́ kí wọ́n gbé Ṣekemu mọ́.

42. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, Abimeleki gbọ́ pé àwọn ará Ṣekemu ń jáde lọ sinu pápá.

43. Ó kó àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, ó pín wọn sí ìsọ̀rí mẹta, wọ́n sì ba níbùba ninu pápá. Bí ó ti rí i pé àwọn eniyan náà ń jáde bọ̀ láti inú ìlú, ó gbógun tì wọ́n, ó sì pa wọ́n.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 9