Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 9:11-27 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ṣugbọn igi ọ̀pọ̀tọ́ dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí n pa èso mi dáradára tí ó ládùn tì, kí n wá jọba lórí yín?’

12. Àwọn igi bá tún lọ sọ́dọ̀ igi àjàrà, wọ́n wí fún un pé kí ó wá jọba lórí àwọn.

13. Ṣugbọn igi àjàrà dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí ń pa ọtí mi, tí ń mú inú àwọn oriṣa ati àwọn eniyan dùn tì, kí n wá jọba lórí ẹ̀yin igi?’

14. Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn igi sọ fún igi ẹ̀gún pé kí ó wá jọba lórí àwọn.

15. Igi ẹ̀gún bá dá àwọn igi lóhùn pé, ‘Tí ó bá jẹ́ pé tinútinú yín ni ẹ fi fẹ́ kí n jọba yín, ẹ wá sábẹ́ ìbòòji mi, n óo sì dáàbò bò yín. Ṣugbọn bí bẹ́ẹ̀ bá kọ́, iná yóo yọ jáde láti ara ẹ̀gún mi, yóo sì jó igi kedari tí ó wà ní Lẹbanoni run.’

16. “Ǹjẹ́ òtítọ́ inú ati ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni ẹ fi fi Abimeleki jọba? Ṣé ohun tí ẹ ṣe sí ìdílé Gideoni tọ́? Gbogbo sísìn tí ó sìn yín, ǹjẹ́ irú ohun tí ó yẹ kí ẹ fi san án fún un nìyí?

17. Nítorí pé baba mi fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu nígbà tí ó ń jà fun yín, ó sì gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Midiani.

18. Ṣugbọn lónìí, ẹ dìde sí ìdílé baba mi, ẹ sì pa aadọrin àwọn ọmọkunrin rẹ̀ lórí òkúta, ẹ wá fi Abimeleki, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ̀ jọba lórí ìlú Ṣekemu, nítorí pé ó jẹ́ ìbátan yín.

19. Nítorí náà, bí ó bá jẹ́ pé pẹlu òtítọ́ inú, ati ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni ẹ fi ṣe ohun tí ẹ ṣe sí Gideoni ati ìdílé rẹ̀ lónìí, ẹ máa yọ̀ lórí Abimeleki kí òun náà sì máa yọ̀ lórí yín.

20. Ṣugbọn bí bẹ́ẹ̀ kọ́, iná yóo jáde láti ara Abimeleki, yóo sì run gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu ati Bẹtimilo. Bẹ́ẹ̀ ni iná yóo jáde láti ara àwọn ará ìlú Ṣekemu ati ti Bẹtimilo, yóo sì jó Abimeleki run.”

21. Jotamu bá sá lọ sí Beeri, ó sì ń gbé ibẹ̀, nítorí ó bẹ̀rù Abimeleki arakunrin rẹ̀.

22. Abimeleki jọba lórí Israẹli fún ọdún mẹta.

23. Ọlọrun rán ẹ̀mí burúkú sí ààrin Abimeleki ati àwọn ara ìlú Ṣekemu. Àwọn ará ìlú Ṣekemu sì dìtẹ̀ mọ́ Abimeleki.

24. Kí ẹ̀san pípa tí Abimeleki pa àwọn aadọrin ọmọ baba rẹ̀ ati ẹ̀jẹ̀ wọn lè wá sórí Abimeleki, ati àwọn ará ìlú Ṣekemu tí wọ́n kì í láyà láti pa wọ́n.

25. Àwọn ará ìlú Ṣekemu bá rán àwọn kan ninu wọn, wọ́n lọ ba ní ibùba ní orí òkè de Abimeleki. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dá gbogbo àwọn tí wọn ń kọjá lọ́nà; ni ìròyìn bá kan Abimeleki.

26. Gaali ọmọ Ebedi ati àwọn arakunrin rẹ̀ kó lọ sí Ṣekemu, àwọn ará ìlú Ṣekemu sì gbẹ́kẹ̀lé e.

27. Àwọn ará ìlú Ṣekemu lọ sinu oko wọn, wọ́n ká èso àjàrà, wọ́n fi pọn ọtí fún wọn. Wọ́n jọ ń ṣe àríyá, wọ́n jọ lọ sí ilé oriṣa wọn, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi Abimeleki ṣe ẹlẹ́yà.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 9