Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 7:9-23 BIBELI MIMỌ (BM)

9. OLUWA sọ fún un ní òru ọjọ́ kan náà pé, “Gbéra, lọ gbógun ti àgọ́ náà, nítorí pé mo ti fi lé ọ lọ́wọ́.

10. Ṣugbọn bí ẹ̀rù bá ń bà ọ láti lọ, mú Pura iranṣẹ rẹ, kí ẹ jọ lọ sí ibi àgọ́ náà.

11. O óo gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, lẹ́yìn náà, o óo ní agbára láti lè gbógun ti àgọ́ náà.” Gideoni bà mú Pura, iranṣẹ rẹ̀, wọ́n jọ lọ sí ìpẹ̀kun ibi tí àwọn tí wọ́n di ihamọra ogun ninu àgọ́ wọn wà.

12. Àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati ti Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìlà oòrùn pọ̀ nílẹ̀ lọ bí eṣú àwọn ràkúnmí wọn kò níye, wọ́n pọ̀ bí iyanrìn etí òkun.

13. Nígbà tí Gideoni dé ibẹ̀, ó gbọ́ tí ẹnìkan ń rọ́ àlá tí ó lá fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan pé, “Mo lá àlá kan, mo rí i tí àkàrà ọkà baali kan ré bọ́ sinu ibùdó àwọn ará Midiani. Bí ó ti bọ́ lu àgọ́ náà, ó wó o lulẹ̀, ó sì dojú rẹ̀ délẹ̀, àgọ́ náà sì tẹ́ sílẹ̀ pẹrẹsẹ.”

14. Ẹnìkejì rẹ̀ dá a lóhùn, ó ní, “Èyí kì í ṣe ohun mìíràn, bíkòṣe idà Gideoni, ọmọ Joaṣi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli. Ọlọrun ti fi Midiani ati gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ lé e lọ́wọ́.”

15. Nígbà tí Gideoni gbọ́ bí ó ti rọ́ àlá yìí, ati ìtumọ̀ rẹ̀, ó yin OLUWA. Ó pada sí ibùdó Israẹli, ó ní, “Ẹ dìde, nítorí OLUWA ti fi àwọn ọmọ ogun Midiani le yín lọ́wọ́.”

16. Ó pín àwọn ọọdunrun (300) náà sí ọ̀nà mẹta, ó fi fèrè ogun ati ìkòkò òfìfo tí wọn fi ògùṣọ̀ sí ninu lé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́.

17. Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa wò mí, kí ẹ sì máa ṣe bí mo bá ti ń ṣe. Nígbà tí mo bá dé ìkangun àgọ́ náà, ẹ ṣe bí mo bá ti ṣe.

18. Nígbà tí èmi ati àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ mi bá fọn fèrè, ẹ̀yin náà ẹ fọn fèrè tiyín ní gbogbo àyíká àgọ́ náà, ẹ óo sì pariwo pé, ‘Fún OLUWA, ati fún Gideoni.’ ”

19. Gideoni ati ọgọrun-un eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá lọ sí ìkangun àgọ́ náà ní òru, nígbà tí àwọn olùṣọ́ mìíràn ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ipò àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀. Wọ́n fọn fèrè, wọ́n sì fọ́ àwọn ìkòkò tí ó wà lọ́wọ́ wọn mọ́lẹ̀.

20. Àwọn ẹgbẹ́ mẹtẹẹta fọn fèrè wọn, wọ́n sì fọ́ ìkòkò tì ó wà lọ́wọ́ wọn. Wọ́n fi iná ògùṣọ̀ wọn sí ọwọ́ òsì, wọ́n sì fi fèrè tí wọn ń fọn sí ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n bá pariwo pé, “Idà kan fún OLUWA ati fún Gideoni.”

21. Olukuluku wọn dúró sí ààyè wọn yípo àgọ́ náà, gbogbo àwọn ọmọ ogun Midiani bá bẹ̀rẹ̀ sí sá káàkiri, wọ́n ń kígbe, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ.

22. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Gideoni fọn ọọdunrun (300) fèrè wọn, Ọlọrun mú kí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá wọn dojú ìjà kọ ara wọn, gbogbo wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí apá Serera. Wọ́n sá títí dé Beti Ṣita, ati títí dé ààlà Abeli Mehola, lẹ́bàá Tabati.

23. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pe àwọn ọkunrin Israẹli jáde láti inú ẹ̀yà Nafutali, ati ti Aṣeri ati ti Manase, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ará Midiani lọ.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 7