Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 4:4-17 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Wolii obinrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Debora aya Lapidotu, ni adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli nígbà náà.

5. Lábẹ́ ọ̀pẹ kan, tí wọ́n sọ ní ọ̀pẹ Debora, tí ó wà láàrin Rama ati Bẹtẹli ní agbègbè olókè ti Efuraimu ní í máa ń jókòó sí, ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli tií máa ń lọ bá a fún ìdájọ́.

6. Ó ranṣẹ pe Baraki, ọmọ Abinoamu, ní Kedeṣi, tí ó wà ní Nafutali, ó wí fún un pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ń pàṣẹ fún ọ pé kí o lọ kó àwọn eniyan rẹ̀ jọ ní òkè Tabori. Kó ẹgbaarun (10,000) eniyan ninu ẹ̀yà Nafutali ati Sebuluni jọ.

7. N óo ti Sisera olórí ogun Jabini jáde láti pàdé rẹ lẹ́bàá odò Kiṣoni pẹlu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, n óo sì fà á lé ọ lọ́wọ́.”

8. Baraki bá dá a lóhùn pé, “Bí o óo bá bá mi lọ ni n óo lọ, bí o kò bá ní bá mi lọ, n kò ní lọ.”

9. Debora dáhùn pé, “Láìṣe àní àní, n óo bá ọ lọ. Ṣugbọn ṣá o, ohun tí o fẹ́ ṣe yìí kò ní já sí ògo fún ọ, nítorí pé, OLUWA yóo fi Sisera lé obinrin kan lọ́wọ́.” Debora bá gbéra, ó bá Baraki lọ sí Kedeṣi.

10. Baraki bá pe àwọn ọmọ Sebuluni ati Nafutali sí Kedeṣi; ẹgbaarun (10,000) ọkunrin ninu wọn ni wọ́n tẹ̀lé Baraki, Debora náà sì bá wọn lọ.

11. Ní àkókò yìí, Heberi ará Keni ti kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn ará Keni yòókù tí wọ́n jẹ́ ìran Hobabu, àna Mose, ó sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Kedeṣi lẹ́bàá igi oaku kan ní Saananimu.

12. Nígbà tí Sisera gbọ́ pé Baraki ti lọ sí orí òkè Tabori,

13. ó kó ẹẹdẹgbẹrun (900) kẹ̀kẹ́ ogun onírin rẹ̀ jọ, ó sì pe àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti Haroṣeti-ha-goimu títí dé odò Kiṣoni.

14. Debora wí fún Baraki pé, “Dìde nítorí pé òní ni ọjọ́ tí OLUWA yóo fi Sisera lé ọ lọ́wọ́. Ṣebí OLUWA ni ó ń ṣáájú ogun rẹ lọ?” Baraki bá sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Tabori pẹlu ẹgbaarun (10,000) ọmọ ogun lẹ́yìn rẹ̀.

15. OLUWA mú ìdàrúdàpọ̀ bá Sisera ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ níwájú Baraki. Bí àwọn ọmọ ogun Baraki ti ń fi idà pa wọ́n, Sisera sọ̀kalẹ̀ ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ.

16. Baraki lépa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun Sisera títí dé Haroṣeti-ha-goimu, wọ́n sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun Sisera láìku ẹyọ ẹnìkan.

17. Ṣugbọn Sisera sá lọ sí àgọ́ Jaeli, aya Heberi, ará Keni, nítorí pé alaafia wà ní ààrin Jabini, ọba Hasori, ati ìdílé Heberi ará Keni.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 4