Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 20:29-37 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Àwọn ọmọ Israẹli bá fi àwọn eniyan pamọ́ ní ibùba, yípo gbogbo Gibea.

30. Àwọn ọmọ Israẹli tún gbógun ti àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ọjọ́ kẹta, wọ́n tò yípo Gibea bíi ti iṣaaju.

31. Àwọn ará Bẹnjamini jáde sí wọn, àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí fi ọgbọ́n tàn wọ́n kúrò ní ìlú; àwọn ará Bẹnjamini tún bẹ̀rẹ̀ sí pa ninu àwọn ọmọ Israẹli bíi ti iṣaaju. Wọ́n pa wọ́n ní ojú òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí Bẹtẹli ati Gibea ati ninu pápá. Àwọn tí wọ́n pa ninu wọ́n tó ọgbọ̀n eniyan.

32. Àwọn ará Bẹnjamini wí fún ara wọn pé, “A tún ti tú wọn ká bíi ti iṣaaju.”Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á sá, kí á sì tàn wọ́n kúrò ninu ìlú wọn, kí wọ́n bọ́ sí ojú òpópó.”

33. Olukuluku àwọn ọmọ Israẹli bá kúrò ní ààyè rẹ̀, wọ́n lọ tò ní Baalitamari. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ba ní ibùba bá jáde kúrò níbi tí wọ́n ba sí ní apá ìwọ̀ oòrùn Geba.

34. Ni ẹgbaarun (10,000) àṣàyàn àwọn jagunjagun ninu àwọn ọmọ Israẹli bá gbógun ti ìlú Gibea. Ogun náà gbóná gidigidi ṣugbọn àwọn ará Bẹnjamini kò mọ̀ pé ewu ńlá súnmọ́ tòsí wọn.

35. OLUWA bá ṣẹgun àwọn ará Bẹnjamini fún àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli pa ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbẹẹdọgbọn ó lé ọgọrun-un (25,100) eniyan ninu àwọn ará Bẹnjamini lọ́jọ́ náà. Gbogbo àwọn tí wọ́n pa jẹ́ jagunjagun tí wọn ń lo idà.

36. Àwọn ọmọ Bẹnjamini rí i pé wọ́n ti ṣẹgun àwọn. Nígbà tí, àwọn ọmọ Israẹli ṣebí ẹni ń sá lọ fún àwọn ara Bẹnjamini, wọ́n ń tàn wọ́n jáde ni, wọ́n sì ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ará wọn tí wọ́n ba ní ibùba yípo Gibea láti gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini.

37. Àwọn tí wọ́n ba ní ibùba yára jáde, wọ́n gbógun ti Gibea, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn ará ìlú náà run.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 20