Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 19:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò tí kò sí ọba ní Israẹli, ọmọ Lefi kan ń gbé apá ibìkan tí ó jìnnà ní agbègbè olókè ti Efuraimu. Ọmọ Lefi yìí ní obinrin kan tí ó jẹ́ ará Bẹtilẹhẹmu ni ilẹ̀ Juda.

2. Èdè-àìyedè kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn mejeeji, obinrin yìí bá kúrò lọ́dọ̀ ọkunrin náà, ó lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Bẹtilẹhẹmu, ó sì ń gbé ibẹ̀ fún nǹkan bí oṣù mẹrin.

3. Lẹ́yìn náà, ọkọ rẹ̀ dìde, ó lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó pada. Ọkunrin yìí mú iranṣẹ kan ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bíi meji lọ́wọ́. Nígbà tí ó dé ilé baba obinrin rẹ̀ yìí, tí baba iyawo rẹ̀ rí i, ó lọ pàdé rẹ̀ tayọ̀tayọ̀.

4. Baba obinrin náà rọ̀ ọ́ títí ó fi wà pẹlu wọn fún ọjọ́ mẹta; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì wà níbẹ̀.

5. Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu wọ́n fẹ́ máa lọ. Ṣugbọn baba ọmọbinrin náà rọ̀ ọ́ pé kí ó jẹ oúnjẹ díẹ̀ kí ó tó máa lọ, kí ó lè lágbára.

6. Àwọn ọkunrin mejeeji bá jókòó, wọ́n jẹ, wọ́n mu, lẹ́yìn náà ni baba ọmọbinrin yìí tún dáhùn pé, “Jọ̀wọ́ kúkú dúró ní alẹ́ yìí kí o máa gbádùn ara rẹ.”

7. Nígbà tí ọkunrin náà gbéra, tí ó fẹ́ máa lọ, baba ọmọbinrin náà rọ̀ ọ́ títí tí ó tún fi dúró.

8. Nígbà tí ó di ọjọ́ karun-un, ọkunrin náà gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu láti máa lọ, baba ọmọbinrin náà tún rọ̀ ọ́ pé kí ó fọkàn balẹ̀, kí ó di ìrọ̀lẹ́ kí ó tó máa lọ. Àwọn mejeeji bá jọ jẹun.

9. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́ ọkunrin náà ati obinrin rẹ̀ ati iranṣẹ rẹ̀ gbéra, wọ́n fẹ́ máa lọ; baba ọmọbinrin náà tún wí fún un pé, “Ṣé ìwọ náà rí i pè ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, jọ̀wọ́ dúró kí ó di ọ̀la. Ilẹ̀ ló ti ṣú yìí, dúró níhìn-ín kí o sì gbádùn ara rẹ, bí ó bá di ọ̀la kí ẹ bọ́ sọ́nà ní òwúrọ̀ kutukutu, kí ẹ sì máa lọ sílé.”

10. Ṣugbọn ọkunrin náà kọ̀, ó ní òun kò ní di ọjọ́ keji. Ó bá gbéra, ó ń lọ, títí tí wọ́n fi dé ibìkan tí ó dojú kọ Jebusi (tí wọ́n yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu); àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ wà lọ́dọ̀ rẹ̀, obinrin rẹ̀ sì wà pẹlu rẹ̀.

11. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jebusi, ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, iranṣẹ rẹ̀ sọ fún un pé, “Jẹ́ kí á dúró ní ìlú àwọn ará Jebusi yìí kí á sì sùn níbẹ̀ lónìí.”

12. Ó dá a lóhùn, ó ní, “A kò ní wọ̀ ní ìlú àjèjì, lọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ọmọ Israẹli, kàkà bẹ́ẹ̀, a óo kọjá lọ sí Gibea.”

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 19