Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 18:9-21 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ gbógun tì wọ́n nítorí pé a ti rí ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tí ó lọ́ràá ni. Ẹ má jẹ́ kí á fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀. Ẹ má jáfara, ẹ wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì gbà á.

10. Nígbà tí ẹ bá lọ, ẹ óo dé ibìkan tí àwọn eniyan ń gbé láìbẹ̀rù, ilẹ̀ náà tẹ́jú. Dájúdájú Ọlọrun ti fi lé yín lọ́wọ́, kò sí ohun tí eniyan ń fẹ́ ní ayé yìí tí kò sí níbẹ̀.”

11. Ẹgbẹta (600) ọkunrin ninu ẹ̀yà Dani tí wọ́n dira ogun gbéra láti Sora ati Eṣitaolu.

12. Wọ́n lọ pàgọ́ sí Kiriati Jearimu ní Juda. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Mahanedani títí di òní olónìí; ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn Kiriati Jearimu.

13. Wọ́n lọ láti ibẹ̀ sí agbègbè olókè ti Efuraimu, wọ́n dé ilé Mika.

14. Nígbà náà ni àwọn ọkunrin marun-un tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ Laiṣi sọ fún àwọn arakunrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ẹ̀wù efodu kan wà ninu àwọn ilé wọnyi ati àwọn ère kéékèèké, ati ère tí wọ́n gbẹ́ tí wọ́n sì yọ́ fadaka bò lórí, nítorí náà, kí ni ẹ rò pé ó yẹ kí á ṣe?”

15. Wọ́n bá yà sibẹ, wọ́n sì lọ sí ilé ọdọmọkunrin ọmọ Lefi, tí ó wà ní ilé Mika, wọ́n bèèrè alaafia rẹ̀.

16. Àwọn ẹgbẹta (600) ọkunrin ará Dani tí wọ́n dira ogun dúró ní ẹnu ibodè.

17. Àwọn marun-un tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà bá wọlé, wọ́n gbé ère dídà, wọn mú ẹ̀wù efodu, wọ́n sì kó àwọn ère kéékèèké ati ère fínfín. Ọdọmọkunrin alufaa yìí sì wà ní ẹnu ibodè pẹlu àwọn ẹgbẹta (600) ọkunrin láti inú ẹ̀yà Dani tí wọ́n ti dira ogun.

18. Nígbà tí àwọn marun-un náà lọ sí ilé Mika tí wọ́n sì kó àwọn ère rẹ̀ ati àwọn nǹkan oriṣa rẹ̀, alufaa náà bi wọ́n léèrè pé, “Irú kí ni ẹ̀ ń ṣe yìí?”

19. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́, pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì tẹ̀lé wa, kí o jẹ́ baba ati alufaa fún wa. Èwo ni ìwọ náà rò pé ó dára jù; kí o jẹ́ alufaa fún ilé ẹnìkan ni tabi fún odidi ẹ̀yà kan ati ìdílé kan ní Israẹli?”

20. Inú alufaa náà bá dùn, ó gbé ẹ̀wù efodu, ó kó àwọn ère kékeré náà ati ère dídà náà, ó ń bá àwọn eniyan náà lọ.

21. Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n ń lọ. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati àwọn ẹrù wọn ń lọ níwájú wọn.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 18