Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 18:13-30 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Wọ́n lọ láti ibẹ̀ sí agbègbè olókè ti Efuraimu, wọ́n dé ilé Mika.

14. Nígbà náà ni àwọn ọkunrin marun-un tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ Laiṣi sọ fún àwọn arakunrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ẹ̀wù efodu kan wà ninu àwọn ilé wọnyi ati àwọn ère kéékèèké, ati ère tí wọ́n gbẹ́ tí wọ́n sì yọ́ fadaka bò lórí, nítorí náà, kí ni ẹ rò pé ó yẹ kí á ṣe?”

15. Wọ́n bá yà sibẹ, wọ́n sì lọ sí ilé ọdọmọkunrin ọmọ Lefi, tí ó wà ní ilé Mika, wọ́n bèèrè alaafia rẹ̀.

16. Àwọn ẹgbẹta (600) ọkunrin ará Dani tí wọ́n dira ogun dúró ní ẹnu ibodè.

17. Àwọn marun-un tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà bá wọlé, wọ́n gbé ère dídà, wọn mú ẹ̀wù efodu, wọ́n sì kó àwọn ère kéékèèké ati ère fínfín. Ọdọmọkunrin alufaa yìí sì wà ní ẹnu ibodè pẹlu àwọn ẹgbẹta (600) ọkunrin láti inú ẹ̀yà Dani tí wọ́n ti dira ogun.

18. Nígbà tí àwọn marun-un náà lọ sí ilé Mika tí wọ́n sì kó àwọn ère rẹ̀ ati àwọn nǹkan oriṣa rẹ̀, alufaa náà bi wọ́n léèrè pé, “Irú kí ni ẹ̀ ń ṣe yìí?”

19. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́, pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì tẹ̀lé wa, kí o jẹ́ baba ati alufaa fún wa. Èwo ni ìwọ náà rò pé ó dára jù; kí o jẹ́ alufaa fún ilé ẹnìkan ni tabi fún odidi ẹ̀yà kan ati ìdílé kan ní Israẹli?”

20. Inú alufaa náà bá dùn, ó gbé ẹ̀wù efodu, ó kó àwọn ère kékeré náà ati ère dídà náà, ó ń bá àwọn eniyan náà lọ.

21. Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n ń lọ. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati àwọn ẹrù wọn ń lọ níwájú wọn.

22. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn jìnnà sí ilé Mika, Mika pe gbogbo àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, wọ́n sì lé àwọn ará Dani bá.

23. Wọ́n kígbe pè wọ́n, àwọn ará Dani bá yipada, wọn bi Mika pé, “Kí ní ń dà ọ́ láàmú tí o fi ń bọ̀ pẹlu ọpọlọpọ eniyan báyìí?”

24. Ó bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ kó àwọn oriṣa mi, tí mo dà, ẹ mú alufaa mi lọ; kí ni ó kù mí kù. Ẹ tún wá ń bi mí pé, Kí ló ń ṣe mí?”

25. Àwọn ará Dani dá a lóhùn, wọ́n ní, “Má jẹ́ kí àwọn eniyan gbọ́ ohùn rẹ láàrin wa, kí àwọn tí inú ń bí má baà pa ìwọ ati gbogbo ìdílé rẹ.”

26. Àwọn ará Dani bá ń bá tiwọn lọ, nígbà tí Mika rí i pé wọ́n lágbára ju òun lọ, ó pada sílé rẹ̀.

27. Lẹ́yìn tí àwọn ará Dani ti kó oriṣa Mika, tí wọ́n sì ti gba alufaa rẹ̀, wọ́n lọ sí Laiṣi, wọ́n gbógun ti àwọn eniyan náà níbi tí wọ́n jókòó sí jẹ́jẹ́ láì bẹ̀rù; wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì dáná sun ìlú wọn.

28. Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà wọ́n sílẹ̀, nítorí pé wọ́n jìnnà sí ìlú Sidoni, wọn kò sì bá ẹnikẹ́ni ní àyíká wọn da nǹkankan pọ̀. Àfonífojì Betirehobu ni ìlú Laiṣi yìí wà. Wọ́n tún un kọ́, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.

29. Wọ́n yí orúkọ ìlú náà pada kúrò ní Laiṣi tí ó ń jẹ́ tẹ́lẹ̀, wọ́n sọ ọ́ ní Dani gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba ńlá wọn tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Israẹli.

30. Àwọn ará Dani gbé ère dídà náà kalẹ̀ fún ara wọn. Jonatani ọmọ Geriṣomu, ọmọ Mose ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n jẹ́ alufaa fún àwọn ẹ̀yà Dani títí di àkókò tí wọ́n kó gbogbo agbègbè wọn ní ìgbèkùn.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 18