Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 16:6-13 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Delila bá pe Samsoni, ó ní, “Jọ̀wọ́, sọ àṣírí agbára rẹ fún mi, ati bí eniyan ṣe lè so ọ́ lókùn kí eniyan sì kápá rẹ.”

7. Samsoni dá a lóhùn pé, “Bí wọ́n bá fi awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, tí kò tíì gbẹ meje dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”

8. Àwọn ọba Filistini bá kó awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, titun, meje, tí kò tíì gbẹ, fún Delila, ó sì fi so Samsoni.

9. Ó ti fi àwọn eniyan pamọ́ sinu yàrá inú. Ó bá pe Samsoni, ó ní, “Samsoni àwọn ará Filistia dé.” Ṣugbọn Samsoni já awọ ọrun náà bí ìgbà tí iná já fọ́nrán òwú lásán. Wọn kò sì mọ àṣírí agbára rẹ̀.

10. Delila tún wí fún Samsoni pé, “Ò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, o sì ń purọ́ fún mi. Jọ̀wọ́ sọ bí eniyan ṣe le dè ọ́ lókùn fún mi.”

11. Ó dá a lóhùn pé, “Tí wọ́n bá fi okùn titun, tí wọn kò tíì lò rí dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”

12. Delila bá mú okùn titun, ó fi dè é, ó sì wí fún un pé, “Samsoni, àwọn ará Filistia dé!” Àwọn tí wọ́n sápamọ́ sì wà ninu yàrá inú. Ṣugbọn Samsoni fa okùn náà já bí ẹni pé fọ́nrán òwú kan ni.

13. Delila tún wí fún Samsoni pé, “Sibẹsibẹ o ṣì tún ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, o tún ń purọ́ fún mi. Sọ fún mi bí eniyan ṣe lè gbé ọ dè.”Ó dá a lóhùn pé, “Bí o bá di ìdì irun meje tí ó wà lórí mi, mọ́ igi òfì, tí o sì dì í papọ̀, yóo rẹ̀ mi, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 16