Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 16:16-23 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Nígbà tí Delila bẹ̀rẹ̀ sí yọ ọ́ lẹ́nu lemọ́lemọ́, tí ó sì ń rọ̀ ọ́ lojoojumọ, ọ̀rọ̀ náà sú Samsoni patapata.

17. Ó bá tú gbogbo ọkàn rẹ̀ palẹ̀ fún Delila, ó ní, “Ẹnìkan kò fi abẹ kàn mí lórí rí, nítorí pé Nasiri Ọlọrun ni mí láti inú ìyá mi wá. Bí wọ́n bá fá irun mi, agbára mi yóo fi mí sílẹ̀, yóo rẹ̀ mí n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”

18. Nígbà tí Delila rí i pé ó ti tú gbogbo ọkàn rẹ̀ palẹ̀ fún òun, ó ranṣẹ pe àwọn ọba Filistini, ó ní, “Ẹ tún wá lẹ́ẹ̀kan sí i, nítorí pé ó ti sọ gbogbo inú rẹ̀ fún mi.” Àwọn ọba Filistini maraarun bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n mú owó náà lọ́wọ́.

19. Delila mú kí Samsoni sùn lórí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó bá pe ọkunrin kan pé kí ó fá ìdì irun mejeeje tí ó wà ní orí Samsoni. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́ níyà, agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀.

20. Ó wí fún un pé, “Samsoni! Àwọn ará Filistia ti dé.” Samsoni bá jí láti ojú oorun, ó ní, “N óo lọ bí mo ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, n óo sì gba ara mi lọ́wọ́ wọn.” Kò mọ̀ pé OLUWA ti fi òun sílẹ̀.

21. Àwọn Filistini bá kì í mọ́lẹ̀, wọ́n yọ ojú rẹ̀, wọ́n mú un wá sí ìlú Gasa, wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n idẹ dè é. Wọ́n ní kí ó máa lọ àgbàdo ninu ilé ẹ̀wọ̀n.

22. Ṣugbọn irun orí rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí kún lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti fá a.

23. Ní ọjọ́ kan, àwọn ọba Filistini kó ara wọn jọ láti rú ẹbọ ńlá kan sí Dagoni, oriṣa wọn, ati láti ṣe àríyá pé oriṣa wọn ni ó fi Samsoni ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 16