Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 16:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ kan, Samsoni lọ sí ìlú Gasa, ó rí obinrin aṣẹ́wó kan níbẹ̀, ó bá wọlé tọ̀ ọ́ lọ.

2. Àwọn kan bá lọ sọ fún àwọn ará Gasa pé Samsoni wà níbẹ̀. Wọ́n yí ilé náà po, wọ́n sì ba dè é níbi ẹnu ọ̀nà bodè ìlú ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Wọ́n dákẹ́ rọ́rọ́, wọ́n ní, “Ẹ jẹ́ kí á dúró títí di ìdájí kí á tó pa á.”

3. Ṣugbọn Samsoni sùn títí di ọ̀gànjọ́ òru. Ní òru náà, ó gbéra, ó gbá ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà mú ati àwọn òpó rẹ̀ mejeeji, ó sì fà á tu pẹlu irin ìdábùú rẹ̀, ó gbé wọn lé èjìká, ó sì rù wọ́n lọ sí orí òkè kan tí ó wà ní iwájú Heburoni.

4. Lẹ́yìn èyí, Samsoni rí obinrin kan tí ó wù ú ní àfonífojì Soreki, ó sì fẹ́ ẹ. Delila ni orúkọ obinrin náà.

5. Àwọn ọba Filistia wá sọ́dọ̀ obinrin yìí, wọ́n ní, “Tan ọkọ rẹ, kí o sì mọ àṣírí agbára rẹ̀, ati ọ̀nà tí a fi lè kápá rẹ̀; kí á lè dì í lókùn kí á sì ṣẹgun rẹ̀. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóo sì fún ọ ní ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka.”

6. Delila bá pe Samsoni, ó ní, “Jọ̀wọ́, sọ àṣírí agbára rẹ fún mi, ati bí eniyan ṣe lè so ọ́ lókùn kí eniyan sì kápá rẹ.”

7. Samsoni dá a lóhùn pé, “Bí wọ́n bá fi awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, tí kò tíì gbẹ meje dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”

8. Àwọn ọba Filistini bá kó awọ tí wọ́n fi ń ṣe ọrun, titun, meje, tí kò tíì gbẹ, fún Delila, ó sì fi so Samsoni.

9. Ó ti fi àwọn eniyan pamọ́ sinu yàrá inú. Ó bá pe Samsoni, ó ní, “Samsoni àwọn ará Filistia dé.” Ṣugbọn Samsoni já awọ ọrun náà bí ìgbà tí iná já fọ́nrán òwú lásán. Wọn kò sì mọ àṣírí agbára rẹ̀.

10. Delila tún wí fún Samsoni pé, “Ò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, o sì ń purọ́ fún mi. Jọ̀wọ́ sọ bí eniyan ṣe le dè ọ́ lókùn fún mi.”

11. Ó dá a lóhùn pé, “Tí wọ́n bá fi okùn titun, tí wọn kò tíì lò rí dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”

12. Delila bá mú okùn titun, ó fi dè é, ó sì wí fún un pé, “Samsoni, àwọn ará Filistia dé!” Àwọn tí wọ́n sápamọ́ sì wà ninu yàrá inú. Ṣugbọn Samsoni fa okùn náà já bí ẹni pé fọ́nrán òwú kan ni.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 16