Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 65:8-25 BIBELI MIMỌ (BM)

8. “Bí eniyan tíí wòye pé ọtí wà lára ìdì èso àjàrà,tí wọn sìí sọ pé, ‘Ẹ má bà á jẹ́,nítorí ohun rere wà ninu rẹ̀,’bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe nítorí iranṣẹ mi,n kò ní pa gbogbo wọn run.

9. N óo mú kí arọmọdọmọ jáde lára Jakọbu,àwọn tí yóo jogún òkè ńlá mi yóo sì jáde láti ara Juda.Àwọn tí mo ti yàn ni yóo jogún rẹ̀,àwọn iranṣẹ mi ni yóo sì máa gbé ibẹ̀.

10. Ilé Ṣaroni yóo di ibùjẹ ẹran,àfonífojì Akori yóo sì di ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn yóo máa dùbúlẹ̀ sí,fún àwọn eniyan mi, tí wọ́n wá mi.

11. “Ṣugbọn níti ẹ̀yin tí ẹ kọ mí sílẹ̀,tí ẹ gbàgbé Òkè Mímọ́ mi,tí ẹ tẹ́ tabili sílẹ̀ fún Gadi, oriṣa Oríire,tí ẹ̀ ń po àdàlú ọtí fún Mẹni, oriṣa Àyànmọ́.

12. N óo fi yín fún ogun pa,gbogbo yín ni ẹ óo sì bọ́ sọ́wọ́ àwọn apànìyàn;nítorí pé nígbà tí mo pè yín, ẹ kò dáhùn,nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹ kò gbọ́,ẹ ṣe nǹkan tí ó burú lójú mi;ẹ yan ohun tí inú mi kò dùn sí.

13. Wò ó, àwọn iranṣẹ mi yóo máa rí oúnjẹ jẹ,ṣugbọn ebi yóo máa pa yín;àwọn iranṣẹ mi yóo mu waini,ṣugbọn òùngbẹ yóo máa gbẹ yín.Àwọn iranṣẹ mi yóo máa yọ̀,ṣugbọn ìtìjú yóo máa ba yín.

14. Àwọn iranṣẹ mi yóo máa kọrin nítorí inú wọn dùn,ṣugbọn ẹ̀yin óo máa kígbe oró àtọkànwá;ẹ óo sì máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, nítorí àròkàn.

15. Orúkọ tí ẹ óo fi sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ miyóo di ohun tí wọn yóo máa fi gégùn-ún.Èmi Oluwa Ọlọrun óo pa yín.Ṣugbọn n óo pe àwọn iranṣẹ mi ní orúkọ mìíràn.

16. Dé ibi pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ tọrọ ibukun ní ilẹ̀ náà,yóo máa tọrọ rẹ̀ ní orúkọ Ọlọrun òtítọ́,ẹnikẹ́ni tí yóo bá sì búra ní ilẹ̀ náà,orúkọ Ọlọrun òtítọ́ ni yóo máa fi búra.Àwọn ìṣòro àtijọ́ yóo ti di ohun ìgbàgbé,a óo sì ti fi wọ́n pamọ́ kúrò níwájú mi.”

17. OLUWA ní,“Mo dá ọ̀run tuntun, ati ayé tuntun;a kò ní ranti àwọn ohun àtijọ́ mọ́,tabi kí wọn sọ sí eniyan lọ́kàn.

18. Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí inú yín ó máa dùn,kí ẹ sì máa yọ títí lae, ninu ohun tí mo dá.Wò ó! Mo dá Jerusalẹmu ní ìlú aláyọ̀,mo sì dá àwọn eniyan inú rẹ̀ ní onínú dídùn.

19. N óo láyọ̀ ninu Jerusalẹmu,inú mi óo sì máa dùn sí àwọn eniyan mi.A kò ní gbọ́ igbe ẹkún ninu rẹ̀ mọ́,ẹnikẹ́ni kò sì ní sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ninu rẹ̀ mọ́.

20. Ọmọ tuntun kò ní kú ní Jerusalẹmu mọ́,àwọn àgbààgbà kò sì ní kú láìjẹ́ pé wọ́n darúgbó kùjọ́kùjọ́.Kàkà bẹ́ẹ̀, ikú ọ̀dọ́ ni a óo máa pe ikú ẹni tí ó bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún.Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún,a óo sọ pé ó kú ikú ègún.

21. Wọn óo kọ́ ilé, wọn óo gbé inú rẹ̀;wọn óo gbin ọgbà àjàrà, wọn óo sì jẹ èso rẹ̀.

22. Wọn kò ní kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé,wọn kò sì ní gbin ọgbà àjàrà fún ẹlòmíràn jẹ.Àwọn eniyan mi yóo pẹ́ láyé bí igi ìrókò,àwọn àyànfẹ́ mi yóo sì jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

23. Wọn kò ní ṣe iṣẹ́ àṣedànù,wọn kò ní bímọ fún jamba;nítorí ọmọ ẹni tí OLUWA bukun ni wọn yóo jẹ́,àwọn ati àwọn ọmọ wọn.

24. Kí wọn tó pè mí, n óo ti dá wọn lóhùn,kí wọn tó sọ̀rọ̀ tán, n óo ti gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ.

25. Ìkookò ati ọmọ aguntan yóo jọ máa jẹ káàkiri;kinniun yóo máa jẹ koríko bíi mààlúù,erùpẹ̀ ni ejò yóo máa jẹ, wọn kò ní máa panilára.Wọn kò sì ní máa panirun lórí òkè mímọ́ mi mọ́.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Aisaya 65