Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Títù 1:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pọ́ọ̀lù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti Àpósítélì Jésù Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, àti ìmọ̀ òtítọ́ irú èyí tí í máa darí ènìyàn sí ìgbé ayé ìwà bí Ọlọ́run—

2. ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ tí ó dúró lórí ìrètí iyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run tí kì í purọ́ ti se ìlérí rẹ̀ ṣáájú kí ayé tó bẹ̀rẹ̀,

3. àti pé ní àkókò tirẹ̀, òun ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn nínú ìwàásù tí a fi lé mi lọ́wọ́ nípa àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa.

4. Sí Títù, ọmọ mi tòótọ́ nínú ìgbàgbọ́ wa kan náà.Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Kírísítì Jésù Olùgbàlà wa.

5. Ìdí tí mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè ni pé kí o lè ṣe àsepé àwọn iṣẹ́ tó sẹ́kù. Mo sì ń rọ̀ ọ́ kí o yan àwọn alàgbà ní ìlú kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí mo ṣe darí rẹ̀.

6. Ẹni tí yóò jẹ́ alàgbà gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onìyàwó kan, ọmọ wọn náà gbọdọ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí kò ní ẹ̀sùn ìwà ipá tàbí ẹ̀sùn àìgbọ́ràn kankan.

7. Alámójútó jẹ́ ẹni tí a gbé iṣẹ́ Ọlọ́run lé lọ́wọ́, nítorí náà, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kankan tàbí agbéraga, oníjà, kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí tàbí alágídí tàbí olójúkòkòrò.

8. Wọ́n ní láti jẹ́ olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, olùfẹ́ ohun tí ó dára. Wọ́n ní láti jẹ́ ẹni tí ó kò ara rẹ̀ ní ìjánu, ẹni dúró sinsin, ọlọ́kàn mímọ́, àti ẹni oníwàtítọ́.

9. Ó gbọdọ̀ di ẹ̀kọ́ nìpa ìdúrósinsin mú dáadáa gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ọ, kí ó lè fi ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Nípa èyí, yóò lè fi ìdí òtítọ́ múlẹ̀ fún àwọn alátakò.

10. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ọlọ̀tẹ̀, afínnú àti ẹlẹ́tàn pàápàá jùlọ láàrin àwọn onílà.

Ka pipe ipin Títù 1