Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 9:3-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nígbà yìí ni àwọn olùkọ́ òfin wí fún ara wọn pé, “Ọkùnrin yìí ń sọ̀rọ̀-òdì!”

4. Jésù sì mọ̀ èrò inú wọn, ó wí pé, “Nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe ń ro búburú nínú yín?

5. Èwo ni ó rọrùn jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ;’ tàbí wí pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn?’

6. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì ni.” Ó sì wí fún arọ náà pé, “Dìde, sì gbé ẹní rẹ, kí o sì máa lọ ilé rẹ.”

7. Ọkùnrin náà sì dìde, ó sì lọ ilé rẹ̀.

8. Nígbà tí ìjọ ènìyàn rí í ẹnu sì yà wọ́n, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, ti ó fi irú agbára báyìí fún ènìyàn.

9. Bí Jésù sì ti ń rékọjá láti ibẹ̀ lọ, o rí ọkùnrun kan ti à ń pè ní Mátíù, ó jókòó ní ibùdó àwọn agbowó-òde, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn,” Mátíù sì dìde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

10. Ó sì ṣe, bí Jésù tí jókòó ti ó ń jẹun nínú ilé Mátíù, sì kíyèsí i, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó-òde àti “ẹlẹ́sẹ̀” wá, wọ́n sì bá a jẹun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

11. Nígbà tí àwọn Farisí sì rí i, wọ́n wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “ ‘Èé ṣe’ tí Olùkọ́ yín fi ń bá àwọn agbowó-òde àti àwọn ẹlẹ́sẹ̀ jẹun pọ̀?”

12. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù gbọ́ èyí, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọ́n le kò wá oníṣègùn bí kò ṣe àwọn tí ara wọn kò dá.

13. Ṣùgbọ́n ẹ lọ kọ́ bí a ti mọ̀ èyí sí: ‘Àánú ni èmi ń fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;’ nítorí èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́sẹ̀.”

14. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù tọ̀ ọ́ wá láti béèrè wí pé, “Èé ṣe tí àwa àti àwọn Farisí fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?”

15. Jésù sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ ilé ìyàwó ha le máa sọ̀fọ̀, nígbà tí ọkọ ìyàwó ń bẹ lọ́dọ̀ wọn? Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó lọ́wọ́ wọn; nígbà náà ni wọn yóò gbààwẹ̀.

16. “Kò sí ẹni tí í fi ìrépé aṣọ tutun lẹ ògbólògbó ẹ̀wù; nítorí èyí tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò ya ní ojú lílẹ̀, aṣọ náà yóò sì ya púpọ̀ sì i ju ti ìṣáájú lọ.

Ka pipe ipin Mátíù 9