Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 8:18-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ẹ̀yin ní ojú, ẹ kò fi ríran? Ẹyín ni etí ẹ kò sí gbọ́ran? Ẹ̀yin kò sì rántí?

19. Nígbà ti mo bu ìṣù búrẹ́dì márùn ún fún ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5000) ènìyàn, agbọ̀n mélòó ni ó kún fún àjẹkù tí ẹ ṣà jọ?”Wọ́n wí pé, “Méjìlá.”

20. “Bákan náà, nígbà tí mo bọ́ ẹgbàajì pẹ̀lú ìṣù àkàrà méje, agbọ̀n mélòó ló kù sílẹ̀ lẹ́yìn àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn wọn?”Wọ́n dáhùn pé, “Ó ku ẹ̀kún agbọ̀n méje.”

21. Ó sì wí fún wọn pé, “È é ha ti ṣe tí kò fi yé yin?”

22. Nígbà tí wọ́n dé Bẹtisáídà, àwọn ènìyàn kan mú afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ kàn án, kí ó sì wò ó sàn.

23. Jésù fa ọkùnrin náà lọ́wọ́, ó sì mú un jáde lọ sí ẹ̀yin ìlú. Ó tu itọ́ sí i lójú. Ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú náà. Ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lè rí ohunkóhun nísinsìn yìí?”

24. Ọkùnrin náà wò àyíká rẹ̀, ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, mo rí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n n kò rí wọn kedere, wọ́n n rìn kiri bí àgékù igi.”

25. Nígbà náà, Jésù tún gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé àwọn ojú ọkùnrin náà, bí ọkùnrin náà sì ti ranjú mọ́ ọn, a dá ìran rẹ̀ padà, ó sì rí gbogbo nǹkan kedere.

26. Jésù sì rán an sí àwọn ẹbí rẹ̀. Ó kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe lọ sí ìlú, kí o má sì sọ fún ẹnikẹni ní ìlú.”

27. Nisinsìn yìí, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò ní Gálílì. Wọ́n sì jáde lọ sí àwọn abúlé ní agbègbè Ṣísáríà Fílípì. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni àwọn ènìyàn rò wí pé mo jẹ́?”

28. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà dáhùn pé, “Àwọn kan rò pé ìwọ ni Jòhánù Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn sọ pé, ìwọ ni Èlíjà tàbí àwọn wòlíì mìíràn àtijọ́ ni ó tún padà wá ṣáyé.”

29. Nígbà náà, Jésù bèèrè, “Ta ni ẹ̀yin gan-an rò pé mo jẹ́?”Pétérù dáhùn pé, “Ìwọ ni Kírísítì náà.”

Ka pipe ipin Máàkù 8