Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 10:23-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ó sì yípadà sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní apákan. Ó ní, “Ìbùkún ni fún ojú tí ń rí ohun tí ẹ̀yin ń rí.

24. Nítorí mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba ni ó ń fẹ́ láti rí ohun tí ẹ̀yin ń rí, wọn kò sì rí wọn, àti láti gbọ́ ohun tí ẹ̀yin ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.”

25. Sì kíyèsí i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, “Olùkọ́, kínni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”

26. Ó sì bi í pé, “Kí ni a kọ sínú ìwé òfin? Bí ìwọ ti kà á?”

27. Ó sì dáhùn wí pé, “ ‘Kí ìwọ fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ’; àti, ‘Ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ ”

28. Ó sì wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn rere: ṣe èyí, ìwọ ó sì yè.”

29. Ṣùgbọ́n ó ń fẹ́ láti da ara rẹ̀ láre, ó wí fún Jésù wí pé, “Ta ha sì ni ẹnìkejì mi?”

30. Jésù sì dáhùn ó wí pé, “Ọkùnrin kan ń ti Jerúsálémù sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán.

31. Ní kòńgẹ́ àkókò yìí ni àlùfáà kan sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ lọ́nà náà: nígbà tí ó sì rí i ó kọjá lọ níhà kejì.

32. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọmọ Léfì kan pẹ̀lú, nígbà tí ó dé ibẹ̀, tí ó sì rí i, ó kọjá lọ níhà kejì.

33. Ṣùgbọ́n ará Samáríà kan, bí ó ti ń re àjò, ó dé ibi tí ó gbé wà; nígbà tí ó sì rí i, àánú ṣe é.

34. Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì di ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti ọtí wáìnì sí i, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti òun tìkalárarẹ̀, ó sì mú un wá sí ilé èrò, a sì ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

35. Nígbà tí ó sì lọ ní ijọ́ kejì, ó fi owó idẹ méjì fún olórí ilé èrò ó sì wí fún un pé, ‘Má a tọ́jú rẹ̀; ohunkóhun tí ìwọ bá sì ná kún un, nígbà tí mo bá padà dé, èmi ó san án fún ọ.’

36. “Nínú àwọn mẹ́tẹ̀èta wọ̀nyí, tani ìwọ rò pé ó jẹ́ ẹnìkejì ẹni tí ó bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà?”

37. Ó sì dáhùn wí pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un.”Jésù sì wí fún un pé, “Lọ, kí o ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́!”

38. Ó sì se, bí wọ́n ti ń lọ, o wọ ìletò kan, obìnrin kan tí a ń pè ní Mátà sì gbà á sí ilé rẹ̀.

39. Ó sì ní arábìnrin kan tí a ń pè ní Màríà tí ó sì jókòó lẹ́bàá ẹṣẹ̀ Jésù, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

40. Ṣùgbọ́n Mátà ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkàn ṣe ìránṣẹ́? Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́.”

41. Ṣùgbọ́n Jésù sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Mátà, Mátà, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀.

42. Ṣùgbọ́n ohun kan ni a kò lè ṣe aláìní, Màríà sì ti yan ipa rere náà tí a kò lè gbà lọ́wọ́ rẹ̀.”

Ka pipe ipin Lúùkù 10