Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 10:11-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. ‘Eruku ìlú yín tí ó kù sí wa lẹ́sẹ̀, a gbọ̀n ọ́n sílẹ̀ fún yín! Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, ìjọba Ọlọ́run kù dẹ̀dẹ̀ sí yín!’

12. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Sódómù ní ìjọ́ náà, ju fún ìlú náà lọ.

13. “Ègbé ni fún ìwọ, Kórásínì! Ègbé ni fún ìwọ Bẹtiṣáídà! Nítorí ìbáṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ agbára tí a ṣe nínú yín, ní Tírè àti Ṣídónì, wọn ìbá ti ronúpìwàdà lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, wọn ìbá sì jókòó nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti nínú eérú.

14. Ṣùgbọ́n yóò sàn fún Tírè àti Sídónì nígbà ìdájọ́ jù fún yín lọ.

15. Àti ìwọ, Kápánáúmù, a ó ha gbé ọ ga dé òkè ọ̀run? A ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ dé isà òkú.

16. “Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi: ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.”

17. Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”

18. Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Sátánì ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá.

19. Kíyèsí i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèé mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì sí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára.

20. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ sí èyí, pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé; a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run!”

21. Ní wákàtí kan náà Jésù yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́: bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sáà yẹ ní ojú rẹ.

22. “Ohun gbogbo ni a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Baba mi; kò sì sí ẹni tí ó mọ ẹni tí ọmọ jẹ́, bí kò ṣe Baba; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wu ọmọ láti fi í hàn fún.”

23. Ó sì yípadà sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní apákan. Ó ní, “Ìbùkún ni fún ojú tí ń rí ohun tí ẹ̀yin ń rí.

24. Nítorí mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba ni ó ń fẹ́ láti rí ohun tí ẹ̀yin ń rí, wọn kò sì rí wọn, àti láti gbọ́ ohun tí ẹ̀yin ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.”

25. Sì kíyèsí i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, “Olùkọ́, kínni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”

26. Ó sì bi í pé, “Kí ni a kọ sínú ìwé òfin? Bí ìwọ ti kà á?”

Ka pipe ipin Lúùkù 10