Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 11:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. A sì fi ìféèfé kan fún mi tí o dàbí ọ̀pá: ẹnìkan sì wí pé, “Dìde, wọn tẹ́ḿpílì Ọlọ́run, àti pẹpẹ, àti àwọn tí ń sìn nínú rẹ̀.

2. Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹ́ḿpìlì sílẹ̀, má si ṣe wọ̀n ọ́n; nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà: ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjì lé lógójì.

3. Èmi ó sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹlẹ̀rìí mi méjèèje, wọn o sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fa ọjọ́ ó-lé-ọgọ́ta nínú aṣọ-ọ̀fọ̀.”

4. Wọ̀nyí ni igi olífì méjì náà, àti ọ̀pá fìtílà méjì náà tí ń dúró níwájú Olúwa ayé.

5. Bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọn lara, iná ó ti ẹnu wọn jáde, a sì pa àwọn ọ̀ta wọn run: bayìí ni a ó sì pa ẹnikẹ́ni tí ó ba ń fẹ́ pa wọn lára run.

6. Àwọn wọ̀nyí ni ó ni agbára láti sé ọ̀run, tí òjò kò fi lè rọ̀ ni ọjọ́ àsọtẹ́lẹ̀ wọn: wọ́n sì ní agbára lórí omi láti sọ wọn di ẹ̀jẹ̀, àti láti fi onírúurú àjàkálẹ̀-àrùn kọlu ayé, nígbàkúgbà tí wọ́n bá fẹ́.

7. Nígbà tí wọn bá sì ti parí ẹ̀rí wọn, ẹranko tí o ń tí inú ọ̀gbun gòkè wá yóò bá wọn jagun, yóò sì ṣẹ́gun wọn, yóò sì pa wọ́n.

8. Òkú wọn yóò sì wà ni ìgboro ìlú ńlá náà tí a ń pè ní Sódómù àti Éjíbítì nípa ti ẹ̀mí, níbi tí a gbé kan Olúwa wọ́n mọ́ àgbélébùú.

9. Fún ijọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ ni àwọn ènìyàn nínú ènìyàn gbogbo àti ẹ̀yà, àti èdè, àti orílẹ̀, wo òkú wọn, wọn kò si jẹ kì a gbé òkú wọn sínú ibojì.

10. Àti àwọn tí o ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì yọ̀ lé wọn lórí, wọn yóò sì ṣe àríyá, wọn ó sì ta ara wọn lọ́rẹ; nítorí tí àwọn wòlíì méjèèjì yìí dá àwọn tí o ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé lóró,

11. Àti lẹ́yìn ijọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí iyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá wọ inú wọn, wọn sì dìde dúró ni ẹṣẹ̀ wọn; ẹ̀rù ńlá sì ba àwọn tí o rí wọn.

Ka pipe ipin Ìfihàn 11