Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 5:27-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Nígbà tí wọn sì mú àwọn àpósítélì dé, wọn mú wọn dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀; olórí àlúfáà sì bi wọ́n léèrè.

28. Ó wí pé, “Àwa kò ha ti kìlọ̀ fún un yín gidigidi pé, kí ẹ má ṣe fi orúkọ yìí kọ́ni. Ṣíbẹ̀ ẹ̀yin ti fi ìkọ́ni yín kún Jerúsálémù, ẹ sì ń pete àti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sí orí wá.”

29. Ṣùgbọ́n Pétérù àti àwọn àpósítélì dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Àwa kò gbọdọ̀ má gbọ́ tí Ọlọ́run ju ti ènìyàn lọ!

30. Ọlọ́run àwọn baba wa jí Jésù dìde kúrò ní ipò òkú, ẹni tí ẹ̀yin pa nípa gbígbé kọ́ sí orí igi.

31. Òun ni Ọlọ́run fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé gẹ́gẹ́ bí Ọmọ-aladé àti Olùgbàlà láti fi ìrònúpìwàdà àti ìdàríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Ísírẹ́lì.

32. Àwa sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti se ẹlẹ́rìí pẹ̀lú, tí Ọlọ́run fifún àwọn tí ó gbà á gbọ́.”

33. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọ́n gbérò láti pa wọ́n.

34. Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àjọ ìgbìmọ̀, tí a ń pè ni Gàmálíẹ́lì, Farisí àti àmofìn, tí ó ní ìyìn gidigidi lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, ó dìde dúró, ó ni kí a mú àwọn àpósítélì bì sẹ́yìn díẹ̀.

35. Ó sì wí fún wọn pé “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ kíyèsí ara yín lóhun tí ẹ̀yin ń pète láti ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí.

36. Nítorí ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí ni Téúdà dìde, ó ń wí pé, ẹni ńlá kan ní òun; ẹni tí ìwọ̀n irínwó ọkùnrin dara wọn pọ̀ mọ́; ṣùgbọ́n a pá a; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ sì túká, tí wọn sí di asán.

37. Lẹ́yìn ọkùnrin yìí ni Júdà ti Gálílì dìde ni àkókò kíka àwọn ènìyàn, ó sì fa ẹni púpọ̀ lẹ́yìn rẹ̀; òun pẹ̀lú ṣègbé; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ ni a fọ́nká.

38. Ǹjẹ́ èmi wí fún un yín nísinsin yìí, Ẹ gáfárà fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, kí ẹ sí fi wọn sílẹ̀, nítorí bí ìmọ̀ tàbí iṣẹ́ yìí bá jẹ́ ti ènìyàn, a ó bì í ṣúbu.

39. Ṣùgbọ́n bí ti Ọlọ́run bá ní, ẹ̀yin kì yóò lè bì í ṣúbu; kí ó má ba à jẹ́ pé, a rí yín bí ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà”

40. Wọ́n sì gbà ìmọ̀ràn rẹ̀. Wọn pe àwọn àpósítélì wọlé, wọ́n lù wọ́n. Wọn sí kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ ni orúkọ Jésù mọ́, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ lọ.

41. Nítorí náà wọn sì lọ kúrò níwájú àjọ ìgbìmọ̀; wọn ń yọ̀ nítorí tí a kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ rẹ̀.

42. Ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ḿpílì àti ni ojúlé dé ojúlé, wọn kò dẹ́kùn kíkọ́ni àti láti wàásù ìyìn rere náà pé Jésù ni Kírísítì

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 5