Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ lọ pẹ̀lú àwọn olúsọ́, ó sì mú àwọn àpósítélì wá. Wọn kò fi ipá múwọn, nítorí tí wọn bẹ̀rù àwọn ènìyàn kí a má ba à sọ wọ́n ní òkúta.