orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gálátíà 2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Àpósítélì Tẹ́wọ́ Gba Pọ́ọ̀lù

1. Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá, ni mo tún gòkè lọ sì Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú Bánábà, mo sì mú Títù lọ pẹ̀lú mi.

2. Mo gòkè lọ ní ìbámu ìfihàn, mo gbé ìyìn rere náà tí mo ń wàásù láàrin àwọn aláìkọlà kalẹ̀ níwájú wọn. Ṣùgbọ́n mo se èyí ní ìkọ̀kọ̀ fún àwọn tí ó jẹ́ olùdarí, ni ẹ̀rù pé mo ń sáré tàbí mo tí sáré ìje mi lásán.

3. Ṣùgbọ́n a kò fi agbára mú Títù tí ó wà pẹ̀lú mi, ẹni tí í ṣe ara Gíríkì láti kọlà.

4. Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nítorí àwọn èké arákùnrin tí wọn yọ́ wọ inú àárin wa láti yọ́ òmìnira wa wò, èyí tí àwa ni nínú Kírísítì Jésù, kí wọn lè mú wa wá sínú ìdè.

5. Fún wọn, a kò tilẹ̀ fí ààyè sílẹ̀, nígbà kan rárá; kí òtítọ́ ìyìn rere lè máa wà títí pẹ̀lú yin.

6. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ó dàbí ẹni pàtàkì—ohunkóhun tí ó wù kì wọn já sí, kò jẹ́ nǹkan kan fún mi; Ọlọ́run kò fi bí ẹnìkẹ́ni se rí se ìdájọ́ rẹ̀—àwọn eniyan yìí kò fi ohunkóhun kún ọ̀rọ̀ mi.

7. Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọn rí i pé a tí fi ìyìn rere tí àwọn aláìkọlà le mi lọ́wọ́, bí a tí fi ìyìn rere tí àwọn onílà lé Pétérù lọ́wọ́.

8. Nítorí Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránsẹ Pétérù gẹ́gẹ́ bí Àpósítélì sí àwọn Júù, òun kan náà ni ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránsẹ mi gẹ́gẹ́ bí Àpósítélì sí àwọn aláìkọlà.

9. Jákọ́bù, Pétérù, àti Jòhánù, àwọn ẹni tí ó dàbí ọ̀wọ̀n, fún èmi àti Bánábà ni ọwọ́ ọ̀tún ìdàpọ̀ nígbà tí wọ́n rí oore-ọ̀fe tí a fi fún mi, wọ́n sì gbà pé kí àwa náà tọ àwọn aláìkọlà lọ, nígbà ti àwọn náà lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù.

10. Ohun gbogbo tí wón bèèrè fún ni wí pé kí a máa rántí àwọn tálákà, ohun kan náà gan-an tí mo ń làkàkà láti ṣe.

Pọ́ọ̀lù Tako Pétérù

11. Ṣùgbọ́n nígbà tí Pétérù wá sí Ańtíókù, mo ta kò ó lójú ara rẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ ẹni tí à bá báwí.

12. Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jákọ́bù wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun; Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fà sẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà.

13. Àwọn Júù tí ó kù pawọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ lati jùmọ̀ ṣe àgàbàgebè, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn sì fi àgàbàgebè wọn si Bánábà lọnà.

14. Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédéé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìyìn rere, mo wí fún Pétérù níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ, tí ì ṣe Júù ba ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn aláìkọlà, è é ṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mu àwọn aláìkọlà láti máa rìn bí àwọn Júù?

15. “Àwa tí i ṣe Júù nípa ìbí, tí kì i sí ì ṣe ‘aláìkọlà ẹlẹ́ṣẹ̀,’

16. Tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì, àní àwa pẹ̀lú gbà Jésù Kírísítì gbọ́, kí a báa lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kírísítì, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre.

17. “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa bá ń wá ọ̀nà láti rí ìdáláre nípa Kírísítì, ó di ẹ̀rí wí pé àwa pẹ́lú jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀, ǹjẹ́ èyí ha jásí wí pé Kírísítì ń ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí ì!

18. Nítorí pé bí mo bá sì tún gbé àwọn ohun tí mo tí wó palẹ̀ ró, mo fí ara mi hàn bí arúfin.

19. Nítorí pé nípa òfin, mo tí di òkú sí òfin, kí èmi lè wà láàyè sí Ọlọ́run.

20. A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kírísítì, èmí kò sì wà láàyè mó, ṣùgbọ́n Kírísítì ń gbé inú mi wíwà tí mo sì wà láàyè nínú ara, mo wà láàyè nínú ìgbàgbọ́ ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkararẹ̀ fún mi.

21. Èmi kò ya oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apákan: nítorí pé bí a bá le ti pasẹ̀ òfin jèrè òdodo, a jẹ́ pé Kírísítì kú lásán.”