Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 4:5-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Àti níhìn yìí pẹ̀lú ó wí pé, “Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.”

6. Nítorí náà bí ó tí jẹ́ pé, ó ku kí àwọn kan wọ inú rẹ̀, àti àwọn tí a tí wàásù ìyìn rere náà fún ní ìṣáajú kò wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbọ́ràn:

7. Àti pé, ó yan ọjọ́ kan, ó wí nínú ìwé Dáfídì pé, “Lònìí,” lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ bẹ́ẹ̀; bí a tí wí niṣáájú,“Lònì-ín bí ẹ̀yín bá gbọ́ ohùn rẹ̀,ẹ má ṣe sé ọkàn yín le.”

8. Nítorí, ìbá ṣe pé Jóṣúà tí fún wọn ní ìsinmi, òun kì bá tí sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìsinmi mìíràn lẹ̀yìn náà,

9. nítorí náà ìsinmi kan kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run.

10. Nítorí pé ẹni tí ó ba bọ́ sínú ìsinmi rẹ̀, òun pẹ̀lú sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀.

11. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á múra gírí láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má baà ṣubú nípa irú àìgbàgbọ́ kan náà.

12. Nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ní agbára, ó sì mu ju idàkídà olójú-méjì lọ, ó sì ń gunni àní títí dé pínpín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti ní oríkèé àti ọ̀rá inú egungun, òun sì ni olùmọ̀ èrò inú àti ète ọkàn.

13. Kò sí ẹ̀dá kan tí kò farahàn níwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni ó wà níhòòhò tí a sì ṣípayá fún ojú rẹ̀, níwájú ẹni tí àwa yóò jíyìn.

14. Ǹjẹ́ bí a ti ní olórí àlùfáà ńlá kan, tí ó ti la àwọn ọ̀run kọjá lọ, Jésù ọmọ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ wa mú ṣinṣin.

15. Nítorí a kò ní olórí àlùfáà tí kò lè ṣàì báni kẹ́dùn nínú àìlera wa, ẹni tí a ti dánwò lọ́nà gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwa, ṣùgbọ́n òun kò dẹ́sẹ̀.

16. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a wá si ibi ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́ pẹ̀lú ìgboyà, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí oore-ọ̀fẹ́ láti máa ranni lọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 4