Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 9:9-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nítorí nínú òfin tí Ọlọ́run fún Mósè, ni a tí kọ ọ́ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń pakà nínú oko rẹ̀ lẹ́nu mọ́.” Ǹjẹ́ màlúù ni Ọlọ́run n ṣe ìtọ́jú rẹ̀ bi?

10. Dájúdájú ó sọ eléyìí fún wa pé, nítorí wa ni a se kọ̀wé yìí kí ẹni tí ń tulẹ̀ lè máa tulẹ̀ ní ìrètí àti ẹni tí ń pakà lè ni ìretí láti ní ipin nínú ìkórè.

11. A ti fún irúgbìn èso ẹ̀mí sìnú ọkàn yín. Ẹ rò pé ó pọ̀jù fún wa tàbí ẹ kà á sí àṣejù, láti béèré fún oúnjẹ àti aṣọ fún àyọrísí iṣẹ́ wa bí?

12. Bí àwọn ẹlòmírán bá ní ẹ̀tọ́ tí ìrànlọ́wọ́ sì wá láti ọ̀dọ̀ yín, àwa ha kọ́ ni ó tọ́ sí jù?Ṣùgbọ́n àwa kò lo agbára yìí ṣùgbọ́n àwa faradà ohun gbogbo, kí àwa má baà ṣe ìdènà fún ìyìn rere Kírísítì.

13. Ǹjẹ́ ó yé e yín pé Ọlọ́run sọ fún àwọn tí ó ń siṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì pé kí wọ́n mú oúnjẹ tàbí àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú wá fún òun, làti fi se ìtọ́ju ara wọn? Àti àwọn tí ń dúró tí pẹpẹ wọn a máa se àjọpín pẹ̀lú pẹpẹ.

14. Lọ́nà kan náà ni Olúwa ti fi àṣẹ lélẹ̀ pé, àwọn tí ń wàásù íyìnrere kí wọn sì máa jẹ́ ní ti ìyìn rere.

15. Ṣíbẹ̀síbẹ̀ n kò ì tí ì lo iru àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí rí. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì kọ lẹ́tà yìí láti fi sọ fún un yín pé, mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà irú nǹkan bẹ̀ẹ́ lọ́wọ́ yín. Kí a sọ òtítọ́, ó sàn fún mi láti kú sínú ebi ju pé kí n sọ ayọ̀ tí mo ní láti wàásù nù.

16. Nítorí pé bí mo ti ń wàásù ìyìn rere, kì í se ohun tí mo lè máa sogo lè. Èmi kò tilẹ̀ le è ṣe é ní, kí a tilẹ̀ sọ pé mo fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ègbé ni fún mi tí mo bá kọ̀ láti wàásù ìyìn rere.

17. Tó bá jẹ́ pé mò ń wàásù tinútinú mi, nígbà náà Olúwa ní ẹ̀bùn pàtàkì fún mi, ṣùgbọ́n tí ń kò bá ṣe é tinútinú mi, mo ṣe àsìlò ìdanilójú tí a ní nínú mi.

18. Ní irú ipò báyìí, kí ni ẹ rò pé èrè mi ni láti jẹ́? Èrè mi ní àgbàyanu ayọ̀ tí mo ń rí gbà nípa ìwàásù ìyìn rere láèná ẹnikẹ́ni lówó, láìbéèrè ẹ̀tọ́ mi lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.

19. Bí mo ti jẹ́ òmìnira tí ń kò sì dara pọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni, mo sọ ara mi di ẹrú lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, láti lè jèrè ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sí i.

20. Nígbà tí mó wà lọ́dọ̀ àwọn Júù, mo dàbí ọ̀kan nínú wọn, kí wọn baà lè tẹ́tí sí ìwàásù ìyìn rere mi àti ki n le jèrè wọn fún Kírísítì. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tó wà lábẹ́ òfin èmi kì í bá wọn jiyàn rárá (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí lábẹ́ òfin), kí èmi lè jèrè àwọn ti ń bẹ lábẹ́ òfin.

21. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin, èmi náà yóò dàbí ẹni tí kò sí lábẹ́ òfin (èmi kì í ṣe aláìlófin sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmí ń bẹ lábẹ́ òfin Kírísítì), kí èmi le jèrè àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin.

22. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera. Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi baà lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí.

23. Mo ṣe èyí láti lè rí ààyè láti wàásù ìyìn rere sí wọn àti fún ìbùkún tí èmi pàápàá ń rí gbà, nígbà tí mo bá rí i pé wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn Kírísítì.

24. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó ní ipa nínú rẹ̀ ni ó máa ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnìkan ṣoṣo ni ń gba ipò kìn-ín-ní. Nítorí náà, ẹ sá eré ìje yín kí ẹ baà le borí.

25. Láti borí nínú eré ìdíje, ẹ ní láti sẹ́ ara yín nínú ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó lè fá yín sẹ́yín nínú sísa gbogbo agbára yín. Wọ́n ń ṣe èyí láti gba adé ìdíbàjẹ́. Ṣùgbọ́n àwa ń sá eré ìje tiwa láti fi gba adé ọ̀run tí kò lè bàjẹ́ láéláé.

26. Nítorí náà, mo ń sá eré ìje lọ sójú àmì, kì í ṣe bí ẹni ti kò dá lóju. Mò ń jà kí n lè borí, kì í ṣe bí ẹni tí ń bá afẹ́fẹ́ jà.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 9