Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 4:6-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ẹ kíyèsí i pé, mo ti fi ara mi àti Àpólò ṣe àpẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe titorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.”

7. Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, è é ti ṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á?

8. Báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba. Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn. Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín: tí a ó sì máa jọba pẹ̀lú yín!

9. Nítorí mo rò pé Ọlọ́run ń fi àwa àpósítélì hàn ní ìkẹyin bí ẹni tí a dá lẹ́bi ikú bí àwọn, nítori tí a fi wá ṣe ìran wò fún àwọn ènìyàn àti àwọn ańgẹ́lì ati gbogbo ayé.

10. Àwa jẹ́ asiwèrè nítorí Kírísítì, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú Kírísítì! Àwa jẹ́ aláìlera, ṣùgbọ́n ẹ̀yín jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ẹni àyẹ́sí, àwa jẹ ẹni ẹ̀gàn!

11. Títí di wákàtí yìí ni a ń rìn kiri nínú ebi àti òùngbẹ, a wọ aṣọ àkísà, tí a sì ń lù wa, tí a kò sì ní ibùgbé kan.

12. Tí a ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́, wọn ń gàn wa, àwa ń súre, wọn ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń forítì i.

13. Wọn ń kẹ́gàn wa, àwa ń bẹ̀bẹ̀. Títí di ìsinsinyìí ni a ti wà bí ohun ẹ̀gbin ayé, bí orí àkìtàn gbogbo ayé.

14. Èmi kò kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí láti fi dójútì yín, ṣùgbọ́n láti kìlọ̀ fún un yín bí àwọn ọmọ mi tí mo yàn fẹ́.

15. Nítorí bí ẹ̀yin tilẹ̀ ní ẹgbààrún olùkọ́ni nínú Kírísítì, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ni baba púpọ̀; nítorí nínú Kírísítì Jésù ni mo jẹ́ baba fún un yín nípasẹ̀ ìyìn rere.

16. Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ máa ṣe àfarawé mi.

17. Nítorí náà ni mo ṣe rán Tìmótíù sí i yín, ẹni tí í ṣe ọmọ mi olùfẹ́ àti olódodo nínú Olúwa, ẹni tí yóò máa mú yín rántí ọ̀nà mi tí ó wà nínú Kírísítì, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ni nínú gbogbo ìjọ níbi gbogbo.

18. Mo mọ̀ pé àwọn mìíràn nínú yín tó ya onígbéraga ènìyàn, tí wọn ń rò pé ẹ̀rù ń bà ni láti wá sọ́dọ̀ yín láti ṣe ẹ̀tọ́ fún un yín.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 4