Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 13:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlúkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí ṣọtẹ́lẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ.

5. Ṣùgbọ́n òun o wí pé, ‘Èmi kí í ṣe wòlíì, àgbẹ̀ ni èmi; nítorí tí a ti fi mí ṣe ìránṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá.’

6. Ẹnìkan ó sì wí fún un pé, ‘Ọgbẹ́ kín ní wọ̀nyí ni ẹ̀yìn rẹ?’ Òun o sì dáhùn pé, ‘Wọ̀nyí ni ibi tí a ti sá mi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi.’

7. “Díde, ìwọ idà, sí olùṣọ́-àgùntàn mi,àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,”ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:“Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn,àwọn àgùntàn a sì túká:èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kékèké.

8. Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀,” ni Olúwa wí,“a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú;ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀.

9. Èmi ó sì mú apá kẹ́ta náà la àárin iná,èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà,èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán góòlu wò:wọn yóò sì pé orúkọ mi,èmi yóò sì dá wọn lóhùn:èmi yóò wí pé, ‘Àwọn ènìyàn mi ni,’àwọn yóò sì wí pé, ‘Olúwa ni Ọlọ́run wa.’ ”

Ka pipe ipin Sekaráyà 13