Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sefanáyà 3:14-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Síónì,kígbé sókè, ìwọ Ísírẹ́lì!Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn,ìwọ ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù.

15. Olúwa ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nìkúrò, ó sì ti ti àwọn ọ̀ta rẹ padà sẹ́yìn. Olúwa, ọba Ísírẹ́lì wà pẹ̀lú rẹ,Ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́.

16. Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jérúsálẹ́mù pé,“Má ṣe bẹ̀rù Síónì;má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀.

17. Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ,Ó ní agbára láti gbà ọ là.Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀;Yóò tún ọ se nínú ìfẹ́ rẹ̀,Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”

18. “Èmi ó kó àwọn tí ó ń banújẹ̀ fún àjọ mímọ́ jọ,àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀;àwọn tí ẹ̀gàn rẹ̀ jásí ẹ̀rù.

19. Ní àkókò náàni èmi yóò dojúkọ àwọntí ń ni yín lára,èmi yóò gba atiro là,èmi yóò sì ṣa àwọn tí ó ti fọ́nká jọ,èmi yóò fi ìyìn àti ọlá fún wọn nígbogbo ilẹ̀ tí a bá ti dójútì wọ́n.

20. Ní àkókò náà ni èmi yóò ṣà yín jọ;Nígbà náà ni èmi yóò mú un yín padà wá sílé.Èmi yóò fi ọlá àti ìyìn fún un yínláàárin gbogbo ènìyàn àgbáyé,nígbà tí èmi yóò yí ìgbèkùn yínpadà bọ sípò ní ojú ara yín,”ni Olúwa wí.

Ka pipe ipin Sefanáyà 3