Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rúùtù 3:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kan, Nóámì, ìyá ọkọ Rúùtù wí fún-un pé, “Ọmọbìnrin mi, ǹjẹ́ kò yẹ kí èmi bá ọ wá ilé ọkọ mìíràn fún ọ, níbi tí wọn yóò ti le è máa tọ́jú rẹ?

2. Wòó, Bóásì ọkùnrin nì tí ìwọ bá àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́, tí í ṣe ìbátan wa, yóò wá láti fẹ́ ọkà ní ilẹ̀-ìpakà rẹ̀ ní àṣálẹ́ yìí.

3. Wẹ̀, kí o sì fi ìpara-olóòórùn dídùn pa ara rẹ, kí o sì wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ilẹ̀-ìpakà tí ó gbé ń pa ọkà, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tí yóò fi jẹ tí yóò sì mu tán.

4. Rí í dájú pé o mọ ibi tí ó sùn sí, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti sùn, lọ kí o sí aṣọ ìbora rẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè kí o sì sùn síbi ẹsẹ̀ náà. Òun yóò sì sọ ohun tí ìwọ yóò ṣe fún ọ.”

5. Rúùtù sì fèsì pé, “Gbogbo ohun tí ìwọ sọ fún mi ni èmi yóò ṣe.”

6. Bẹ́ẹ̀ ni Rúùtù lọ sí ilẹ̀-ìpakà tí ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún-un, pé kí o se.

7. Nígbà tí Bóásì parí jíjẹ àti mímu tán, tí ọkàn rẹ̀ sì kún fún ayọ̀. Ó lọ, ó sì dùbúlẹ̀ ní ẹ̀yìn ọkà bálì tí wọ́n kó jọ. Rúùtù yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibẹ̀, ó sí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè, ó sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.

8. Ó sì ṣe nígbà tí ọkùnrin náà tají ní àárin òru, ẹ̀rú bàá, ó sì yí ara padà, ó sì ṣàkíyèsí obìnrin kan tí ó sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.

9. Ó sì béèrè pé, “Ta ni ìwọ í ṣe?”Rúùtù sì fèsì wí pé, “Èmi ni Rúùtù, ìránṣẹ́-bìnrin rẹ. Da etí aṣọ rẹ bò mí, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó le è rà mí padà.”

Ka pipe ipin Rúùtù 3