orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rúùtù 3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Rúùtù Àti Bóásì Ní Ilẹ̀ Ìpakà

1. Ní ọjọ́ kan, Nóámì, ìyá ọkọ Rúùtù wí fún-un pé, “Ọmọbìnrin mi, ǹjẹ́ kò yẹ kí èmi bá ọ wá ilé ọkọ mìíràn fún ọ, níbi tí wọn yóò ti le è máa tọ́jú rẹ?

2. Wòó, Bóásì ọkùnrin nì tí ìwọ bá àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́, tí í ṣe ìbátan wa, yóò wá láti fẹ́ ọkà ní ilẹ̀-ìpakà rẹ̀ ní àṣálẹ́ yìí.

3. Wẹ̀, kí o sì fi ìpara-olóòórùn dídùn pa ara rẹ, kí o sì wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ilẹ̀-ìpakà tí ó gbé ń pa ọkà, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tí yóò fi jẹ tí yóò sì mu tán.

4. Rí í dájú pé o mọ ibi tí ó sùn sí, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti sùn, lọ kí o sí aṣọ ìbora rẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè kí o sì sùn síbi ẹsẹ̀ náà. Òun yóò sì sọ ohun tí ìwọ yóò ṣe fún ọ.”

5. Rúùtù sì fèsì pé, “Gbogbo ohun tí ìwọ sọ fún mi ni èmi yóò ṣe.”

6. Bẹ́ẹ̀ ni Rúùtù lọ sí ilẹ̀-ìpakà tí ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún-un, pé kí o se.

7. Nígbà tí Bóásì parí jíjẹ àti mímu tán, tí ọkàn rẹ̀ sì kún fún ayọ̀. Ó lọ, ó sì dùbúlẹ̀ ní ẹ̀yìn ọkà bálì tí wọ́n kó jọ. Rúùtù yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibẹ̀, ó sí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè, ó sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.

8. Ó sì ṣe nígbà tí ọkùnrin náà tají ní àárin òru, ẹ̀rú bàá, ó sì yí ara padà, ó sì ṣàkíyèsí obìnrin kan tí ó sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.

9. Ó sì béèrè pé, “Ta ni ìwọ í ṣe?”Rúùtù sì fèsì wí pé, “Èmi ni Rúùtù, ìránṣẹ́-bìnrin rẹ. Da etí aṣọ rẹ bò mí, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó le è rà mí padà.”

10. Bóásì sì wí fún-un pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ, ọmọbìnrin mi. Ìfẹ́ tí o fi hàn yí ti pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí ó ti jẹ́ wí pé ìwọ kò lọ láti wá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bóyá ọlọ́rọ̀ tàbí talákà.

11. Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ìwọ ọmọbìnrin mi, má bẹ̀rù. Èmi yóò sì ṣe ohun gbogbo tí o béèrè fún ọ. Gbogbo ènìyàn ni ó mọ̀ ọ́ ní obìnrin oníwà rere.

12. Nítòótọ́ ni wí pé èmi jẹ́ ìbátan tí ó sún mọ́ ọ, ṣùgbọ́n ìbátan kan wà tí ó sún mọ́ ọ ju ti tèmi lọ.

13. Dúró síbí títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, bí ó bá sì di òwúrọ̀ tí ọkùnrin náà sì ṣe tan láti ṣe ìràpadà, ó dára kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí Olúwa ti ń bẹ láàyè nígbà náà ni èmi yóò ṣe ìràpadà, sùn sí ìhín títí ilẹ̀ yóò fi mọ́.”

14. Ó sì sùn ní ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀, ṣùgbọ́n, ó dìde ní ìdájí kùtùkùtù kí ẹnìkín-ín-ní tó le è dá ẹnìkejì mọ̀. Bóásì sì sọ fún-un wí pé, “Má ṣe jẹ́ kí ó di mímọ̀ wí pé obìnrin kan wá sí ilẹ̀-ìpakà.”

15. Ó sì tún wí fún-un pé, “Mú aṣọ ìborùn rẹ tí o dà bora, kí o tẹ̀ ẹ sílẹ̀.” Rúùtù sì ṣe bẹ́ẹ̀, Bóásì sì wọn òṣùwọ̀n ọkà bálì mẹ́fà sí i, ó sì gbé e rù ú. Nígbà náà ni ó padà sí ìgboro.

16. Nígbà tí Rúùtù dé ilé, Náómì, ìyá ọkọ sì bí léèrè pé, “Báwo ni ó ti rí, ọmọbìnrin mi?”Nígbà náà ni ó sì sọ gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún-un, fún ìyá ọkọ rẹ̀.

17. Ó fi kún-un wí pé, “Ó sọ fún mi wí pé, ‘Má ṣe padà sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ ní ọwọ́ òfo, nítorí náà ó fún mi ní ìwọ̀n ọkà bálì mẹ́fà.’ ”

18. Náómì sì wí fún-un pé, “Dúró, ọmọbìnrin mi títí tí ìwọ yóò fi mọ bí ohun gbogbo yóò ti rí. Nítorí pé ọkùnrin náà kò ní sinmi títí tí ọ̀rọ̀ náà yóò fi yanjú lónìí.”