orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rúùtù 1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Náómì àti Rúùtù

1. Ní ìgbà tí àwọn onídaájọ́ ń ṣe àkóso ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ìyàn kan mú ní ilẹ̀ náà, ọkùnrin kan láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà, òun àti aya rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjì lọ láti máa gbé ní ilẹ̀ Móábù fún ìgbà díẹ̀.

2. Orúkọ ọkùnrin náà ń jẹ́ Elimélékì, orúkọ ìyàwó rẹ̀ ni Náómì, orúkọ àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì sì ni Málónì àti Kílíónì àwọn ará Éfúrétà, ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà. Wọ́n sì lọ sí ilẹ̀ Móábù, wọ́n ń gbé níbẹ̀.

3. Ní àsìkò tí wọ́n ń gbé ibẹ̀, Elimélékì, ọkọ Náómì kú, ó sì ku òun (Náómì) pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì.

4. Wọ́n sì fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ará Móábù méjì, orúkọ, ọ̀kan ń jẹ́ Órípà, èkejì sì ń jẹ́ Rúùtù. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti gbé níbẹ̀ fún bí ọdún mẹ́wàá,

5. Málónì àti Kílíónì náà sì kú, Náómì sì wà láìsí ọkọ tàbí ọmọ kankan fún-un mọ́.

6. Nígbà tí Náómì gbọ́ ní Móábù tí ó wà wí pé Olúwa ti bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò nípa fí fún wọn ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ. Ó sì dìde pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì láti padà sí ìlú rẹ̀.

7. Òun pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì ni wọ́n jọ fi ibi tí ó ń gbé sílẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò wọn padà sí ilẹ̀ Júdà.

8. Ṣùgbọ́n ní ojú ọ̀nà, Náómì wí fún àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì pé, “Kí ẹnikọ̀ọ̀kan yín padà sí ilé ìyá rẹ̀. Kí Olúwa ṣe àánú fún yín bí ẹ ti ṣe sí èmi àti àwọn ọkọ yín tí ó kú.

9. Kí Olúwa kí ó fi yín lọ́kàn balẹ̀ ní ilé ọkọ mìíràn.”Náómì sì fi ẹnu kò wọ́n ní ẹnu wí pé “Ó dìgbà,” Wọ́n sì sunkún kíkan kíkan.

10. Wọ́n sì wí fún-un pé, “Rárá, a ó bà ọ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”

11. Ṣùgbọ́n Náómì dáhùn wí pé, “Ẹ padà sílé ẹ̀yin ọmọ mi. Nítorí kí ni ẹ fi fẹ́ wá pẹ̀lú mi? Ṣé mo tún le bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn ni, tí ó le se ọkọ yin?

12. Ẹ padà sílé, ẹ̀yin ọmọ mi, mo ti dàgbà jù láti ní ọkọ mìíràn. Bí mo ti lẹ̀ ní èrò wí pé ìrètí sì wà fún mi, tí mo sì fẹ́ ọkọ mìíràn lónìí tí mo sì bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn,

13. ṣé ẹ̀yin le è dúró dìgbà tí wọ́n bá dàgbà láì fẹ́ ọkọ mìíràn nítorí wọn ni? Rárá, ẹ̀yin ọmọbìnrin mi. Ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún mi ju bí ó ti jẹ́ fún ẹ̀yin lọ nítorí pé ọwọ́ Olúwa ti fìyà jẹ mi lọ́nà tó pamí lára gidi.”

14. Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n tún sunkún kíkorò. Nígbà náà ní Órípà fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ ní ẹnu wí pé ó dìgbà, ṣùgbọ́n Rúùtù dì mọ́ ọn síbẹ̀.

15. Náómì wí pé, “Wòó, arábìnrin rẹ ti padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti òrìṣà rẹ̀, ìwọ náà padà pẹ̀lú rẹ̀.”

16. Ṣùgbọ́n Rúùtù dáhùn wí pé, “Má ṣe rọ̀ mí láti fi ọ́ sílẹ̀ tàbí láti padà lẹ́yìn rẹ. Ibi tí o bá lọ ní èmi yóò lọ, ibi ti ó bá dúró ni èmi yóò dúró, àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run, mi,

17. Nibi tí o bá kú sí ni èmi yóò kú sí, níbẹ̀ ni wọn yóò sì sin mí sí. Kí Olúwa jẹ mí ní ìyà tí ó lágbára, bí ohunkóhun bí kò ṣe ikú bá yà wá.”

18. Nígbà tí Náómì rí i wí pé Rúùtù ti pinnu láti tẹ̀lé òun kò rọ̀ láti padà mọ́.

19. Àwọn méjèèjì sì ń lọ títí wọ́n fi dé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, ariwo ìpadàbọ̀ wọn gba ìlú kan, àwọn obìnrin ibẹ̀ sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Náómì ni èyí bí?”

20. Náómì sì dáhùn wí pé, “Ẹ má ṣe pè mí ní Náómì. Ẹ pè mí ní Márà (Ìkorò), nítorí wí pé Olódùmarè ti mú kí ayé mi di kíkorò.

21. Mo jáde ní kíkún, ṣùgbọ́n Olúwa mú mi padà ní òfo. Nítorí náà kíń ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Náómì, nígbà tí Olódùmarè ti kọ̀ mí sílẹ̀, tí ó sì mú ìdààmú bá mi?”

22. Báyìí ni Náómì ṣe padà láti Móábù pẹ̀lú Rúùtù, ará Móábù ìyàwó ọmọ rẹ̀. Wọ́n gúnlẹ̀ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà bálì.