Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 12:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nígbà tí ilẹ̀kùn sí ìgboro yóò tìtí ariwo ọlọ yóò dákẹ́;nígbà tí àwọn ènìyàn yóò dìde sí ariwo àwọn ẹyẹṣùgbọ́n gbogbo orin wọn yóò máa lọ ilẹ̀.

5. Nígbà tí ènìyàn yóò bẹ̀rù ibi gígaàti ti ìfarapa ní ìgboro;nígbà tí igi álímọ́ǹdì yóò tannáàti tí ẹlẹ́ǹgà yóò wọ́ ara rẹ̀ lọtí ìfẹ́ kò sì ní ru ṣókè mọ́nígbà náà ni ènìyàn yóò lọ ilé rẹ́ ayérayétí àwọn aṣọ̀fọ̀ yóò máa rìn kiri ìgboro.

6. Rántí rẹ̀—kí okùn fàdákà tó já,tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́;kí ìṣa tó fọ́ níbi ìṣun,tàbí kí àyíká-kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga.

7. Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà rí,tí ẹ̀mí yóò sì padà ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni.

8. “Aṣán! Aṣán!” ni Oníwàásù wí.“Gbogbo rẹ̀ aṣán ni!”

9. Kì í ṣe wí pé Oníwàásù jẹ́ ọlọ́gbọ́n nìkan, ṣùgbọ́n ó tún kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀. Ó rò ó dáradára ó sì ṣe àwárí, ó sì gbé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ òwe kalẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ.

10. Oníwàásù wádìí láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀nà, ohun tí ó kọ sì dúró ṣinṣin ó sì jẹ́ òtítọ́.

Ka pipe ipin Oníwàásù 12