Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 9:41-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. Ábímélékì dúró sí Árúmà, nígbà tí Ṣébúlù lé Gáálì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kúrò ni Ṣékémù, kò sì jẹ́ kí wọ́n gbé Ṣékémù mọ́.

42. Ní ọjọ́ kejì àwọn ará Ṣékémù sì jà lọ́ sí oko, ẹnìkan ló ṣe òfófó rẹ̀ fún Ábímélékì.

43. Ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀, ó pín wọn sí ẹgbẹ́ mẹ́ta ó sì sá pamọ́ sí inú oko. Nígbà tí ó sì rí tí àwọn ènìyàn náà ń jáde kúrò nínú ìlú, ó dìde ó gbógun tì wọ́n.

44. Ábímélékì àti àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sáré síwájú, wọ́n gba ẹnu ibodè ìlú náà, wọ́n sì dúró níbẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ méjì tókù sì sáré sí àwọn tó wà ní oko wọ́n sì gbógun tì wọ́n.

45. Ní gbogbo ọjọ́ náà ni Ábímélékì fi bá àwọn ará ìlú náà jà, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa àwọn ènìyàn ìlú náà ó wó ìlú náà palẹ̀ pátapáta ó sì fọ́n iyọ̀ sí i.

46. Àwọn ènìyàn ilé ìṣọ́ Ṣékémù gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sá lọ fún ààbò sí inú ilé ìsọ́ agbára Ọlọ́run Bérítì (El-Bérítì).

47. Nígbà tí wọ́n sọ fún Ábímélékì pé àwọn ènìyàn ilé ìṣọ́ Ṣékémù kó ara wọn jọ pọ̀.

48. Òun àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gun òkè Sálímónì lọ. Ó gé àwọn ẹ̀ka díẹ̀ pẹ̀lú àáké, ó gbé àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí sí èjìká rẹ̀. Ó sọ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe ohun tí ẹ rí tí mo ń ṣe yìí ní kíákíá.”

49. Báyìí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gé àwọn ẹ̀ka igi wọn tẹ̀lé Ábímélékì. Wọ́n kó wọn ti ilé ìṣọ́ agbára níbi tí àwọn ènìyàn sá pamọ́ sí wọ́n sì fi iná síi pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ó tó ẹgbẹ̀rún ènìyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin sì kú.

50. Ábímélékì tún lọ sí Tébésì, ó yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 9