Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 6:3-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ní ìgbàkúgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ti gbin ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Mídíánì, àwọn ará Ámélékì àti àwọn ará ìlà oòrùn mìíràn yóò wá láti bá wọn jà.

4. Wọn yóò tẹ̀dó sí orí ilẹ̀ náà, wọn a sì bá irúgbìn wọ̀nyí jẹ́ títí dé Gásà, wọn kì í sì í fi ohun alààyè kankan ṣílẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kìbáà ṣe àgùntàn, màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

5. Wọn a máa wá pẹ̀lú ohun ọ̀sìn wọn àti àwọn àgọ́ wọn, wọn a sì dàbí eṣú nítorí i púpọ̀ wọn. Ènìyàn kò sì lè ka iye àwọn ènìyàn náà bí ni àwọn ẹran ọ̀sìn, wọ́n pọ̀ débi pé wọn kò ṣe é kà ní iye, wọn a bo ilẹ̀ náà wọn a sì jẹ ẹ́ run.

6. Àwọn ará Mídíánì sì pọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú, wọ́n sọ wọ́n di òtòsì àti aláìní, fún ìdí èyí wọ́n ké pe Olúwa nínú àdúrà fún ìrànlọ́wọ́.

7. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Olúwa nítorí àwọn ará Mídíánì.

8. Olúwa fi etí sí igbe wọn, ó sì rán wòlíì kan sí wọn. Ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: mo mú yín gòkè ti Éjíbítì wá, láti oko ẹrú.

9. Mo gbà yín kúrò nínú agbára Éjíbítì àti kúrò ní ọwọ́ gbogbo àwọn aninilára yín. Mo lé wọn kúrò ní iwájú yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fún yín.

10. Mo wí fún un yín pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín: ẹ má ṣe sin àwọn òrìṣà àwọn ará Ámórì, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́ràn sí ohun tí mo sọ.”

11. Ní ọjọ́ kan ańgẹ́lì Olúwa wá, ó sì jókòó ní abẹ́ igi óákù ófírà èyí ti ṣe ti Jóásìu ará Ábíésérì, níbi tí Gídíónì ọmọ rẹ̀ ti ń lu ọkà jéró, níbi ìpọn ọtí wáìnì láti fi pamọ́ kúrò níwájú àwọn ará Mídíánì.

12. Nígbà tí ańgẹ́lì Olúwa fara han Gídíónì, ó wí fún un pé, “Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, akọni ológun.”

13. Gídíónì dáhùn pé, Alàgbà, bí Olúwa bá wà pẹ̀lú wa, kí ló dé tí gbogbo ìwọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbi gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ tí àwọn baba wa ròyìn rẹ̀ fún wa nígbà tí wọ́n wí pé, “Olúwa kò ha mú wa gòkè láti ilẹ̀ Éjíbítì wá? Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Mídíánì lọ́wọ́.”

14. Olúwa sì yípadà sí i, ó sì wí fún un pé, “Lọ nínú agbára tí o ní yìí, kí o sì gba àwọn ará Ísírẹ́lì sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì. Èmi ni ó ń rán ọ lọ.”

15. Gídíónì sì dáhùn pé, “Alàgbà Báwo ni èmi ó ṣe gba Ísírẹ́lì là? Ìdílé mi ni ó jẹ́ aláìlera jù ní Mànásè, àti pé èmi ni ó sì kéré jù ní ìdílé bàbá mi.”

16. Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì pa gbogbo àwọn ará Mídíánì láì ku ẹnìkankan.”

17. Gídíónì sì dáhùn pé, nísinsìn yìí tí mo bá bá ojúrere rẹ pàdé, fún mi ní àmì pé ìwọ ni ń bá mi sọ̀rọ̀.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 6