Onídájọ́ 6:11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Ní ọjọ́ kan ańgẹ́lì Olúwa wá, ó sì jókòó ní abẹ́ igi óákù ófírà èyí ti ṣe ti Jóásìu ará Ábíésérì, níbi tí Gídíónì ọmọ rẹ̀ ti ń lu ọkà jéró, níbi ìpọn ọtí wáìnì láti fi pamọ́ kúrò níwájú àwọn ará Mídíánì.