Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 20:9-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ohun tí àwa yóò se sí Gíbíà ní yìí: Àwa yóò lọ kọlù ú bí ìbò bá ṣe darí wa.

10. A ó ò mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn ún nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì àti ọgọ́rùn ún (100) láti inú ẹgbẹ̀rún (1000) kan àti ẹgbẹ̀rún kan láti inú ẹgbẹ̀rún ún mẹ́wàá (10,000) láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun. Yóò sì ṣe nígbà tí àwọn jagunjagun bá dé Gíbíà ti àwọn ará Bẹ́ńjámínì, wọn yóò fún wọn ní ohun tí ó bá tọ́ sí wọn fún gbogbo ìwà búburú àti ìwà ìtìjú tí wọ́n ṣe yìí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.”

11. Báyìí ni gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì para pọ̀ ṣọ̀kan bí ọkùnrin kan ṣoṣo wọ́n sì dìde sí ìlú náà.

12. Àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì wí pé, “Kí ni ẹ̀rí sí ìwà búburú yìí tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárin yín?

13. Nítorí náà ẹ mú àwọn ẹni ibi ti Gíbíà yìí wá fún wa, kí àwa lé pa kí a sì fọ ìṣe búburú yìí mọ́ kúrò ní Ísírẹ́lì.”Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì kò fetí sí ti àwọn arákùnrin wọn ọmọ Ísírẹ́lì.

14. Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú wọn sí Gíbíà láti bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà.

15. Ní ẹṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ àwọn ará Bẹ́ńjámínì kó ẹgbàá mẹ́talá (26,000) àwọn ọmọ ogun tí ń lọ dájọ́ láti àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin nínú àwọn tí ń gbé Gíbíà.

16. Ní àárin àwọn ọmọ ogun wọ̀nyí ni ó ti ní àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin tí wọ́n ń lo ọwọ́ òsì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dára débi pé wọ́n lè fi kànnàkànnà ba fọ́nrán òwú ní àìtàṣé (wọ́n jẹ́ ata má tàṣe).

17. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì, yàtọ̀ sí àwọn ará Bẹ́ńjámínì, ka ogún ọ̀kẹ́ àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà.

18. Àwọn ọmọ Ísirẹ́lì lọ sí Bẹ́tẹ́lì (ilé Ọlọ́run) wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Wọ́n wí pé, “Ta ni nínú wa tí yóò kọ́ kojú àwọn ará Bẹ́ńjámínì láti bá wọn jà?” Olúwa dáhùn pé, “Júdà ni yóò kọ́ lọ.”

19. Àwọn ọmọ Ísirẹ́lì dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì dóti Gíbíà (wọ́n tẹ̀gùn sí ẹ̀bá Gíbíà).

20. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì jáde lọ láti bá àwọn ará Bẹ́ńjámínì jà wọ́n sì dúró ní ipò ogun sí wọn ní Gíbíà.

21. Àwọn ọmo Bẹ́ńjámínì sì jáde láti Gíbíà wá wọ́n sì pa àwọn ọmọ ẹgbàá mọ́kànlá ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ojú ogun ní ọjọ́ náà.

22. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì mú ara wọn lọ́kàn le, wọ́n sì tún dúró sí ipò wọn ní ibi tí wọ́n dúró sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 20