Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 13:13-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ańgẹ́lì Olúwa náà dáhùn wí pé, “Aya rẹ gbọdọ̀ ṣe gbogbo ohun tí mo ti sọ fún un

14. kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti inú èṣo àjàrà jáde wá, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn tàbí jẹ ohunkóhun tí ó bá jẹ́ aláìmọ́. Ó ní láti ṣe ohun gbogbo tí mo ti pa láṣẹ fún un.”

15. Mánóà sọ fún ańgẹ́lì Olúwa náà pé, “Jọ̀wọ́ dára dúró títí àwa yóò fi pèṣè ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan fún ọ.”

16. Ańgẹ́lì Olúwa náà dá Mánóà lóhùn pé, “Bí ẹ̀yin tilẹ̀ dá mi dúró, Èmi kì yóò jẹ ọ̀kankan nínú oúnjẹ tí ẹyin yóò pèṣè. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá fẹ́ ẹ pèṣè ọrẹ ẹbọ ṣíṣun, kí ẹ sì fi rúbọ sí Olúwa.” (Mánóà kò mọ̀ pé ańgẹ́lì Olúwa ní i ṣe.)

17. Mánóà sì béèrè lọ́wọ́ ańgẹ́lì Olúwa náà pé, “Kí ni orúkọ rẹ, kí àwa bá à lè fi ọlá fún ọ nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ?”

18. Ṣùgbọ́n ańgẹ́lì Olúwa náà dáhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ ń béèrè ọrúkọ mi? Ìyanu ni, ó kọjá ìmọ̀.”

19. Lẹ́yìn náà ni Mánóà mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọkà, ó sì fi rúbọ lórí àpáta kan sí Olúwa. Nígbà tí Mánóà àti ìyàwó dúró tí wọn ń wò Olúwa ṣe ohun ìyanu kan.

20. Bí ẹ̀là ahọ́n iná ti là jáde láti ibi pẹpẹ ìrúbọ náà sí ọ̀run, ańgẹ́lì Olúwa gòkè re ọ̀run láàárin ahọ́n iná náà. Nígbà tí wọ́n rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Mánóà àti aya rẹ̀ wólẹ̀ wọ́n sì dojú bolẹ̀.

21. Nígbà tí ańgẹ́lì Olúwa náà kò tún fi ara rẹ̀ han Mánóà àti aya rẹ̀ mọ́, Mánóà wá mọ̀ pé ańgẹ́lì Olúwa ni.

22. Mánóà sọ fún aya rẹ̀ pé, “Dájúdájú àwa yóò kú nítorí àwa ti fi ojú rí Ọlọ́run.”

23. Ṣùgbọ́n ìyàwó rẹ̀ dáhùn pé, “Bí Olúwa bá ní èrò àti pa wá kò bá tí gba ọrẹ ṣísun àti ọrẹ ọkà wa, tàbí fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn wá tó sọ nǹkan ìyanu yìí fún wa.”

24. Obínrìn náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ṣáḿsónì. Ọmọ náà dàgbà Olúwa sì bùkún un.

25. Ẹ̀mí Olúwa sì bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nígbà tí ó wà ní Máháne-dánì ní agbede-méjì Sórà àti Ésítaólì.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 13