Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 1:11-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Lẹ́yìn èyí wọ́n tẹ̀ṣíwájú láti bá àwọn tí ń gbé Débírì jagun (orúkọ Débírì ní ìgbà àtijọ́ ni Kíríátì-Ṣéférì tàbí ìlú àwọn ọ̀mọ̀wé).

12. Kélẹ́bù sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́ ṣíwájú ogun tí Kíríátì-Ṣáférì tí ó sì Ṣẹ́gun rẹ̀ ni èmi ó fún ní ọmọbìnrin mi Ákíṣà gẹ́gẹ́ bí aya.”

13. Ótíníẹ́lì ọmọ Kénásì àbúrò Kélẹ́bù ṣíwájú, wọ́n sì kọ lu ìlú náà, ó sì fún un ní Ákíṣà gẹ́gẹ́ bí aya.

14. Ní ọjọ́ kan nígbà tí Ákíṣà wá sí ọ̀dọ̀ Ótíníélì, ó rọ ọkọ rẹ̀ láti tọrọ oko lọ́wọ́ Kélẹ́bù baba rẹ̀. Nígbà tí Ákíṣà ti sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ Kélẹ́bù bi í léèrè pé, “Kí ni o ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ.”

15. Ákíṣà sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojú rere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní Gúúsù (gúṣù) fún mi ní ìṣun omi náà pẹ̀lú.” Kélẹ́bù sì fún un ní ìṣun òkè àti ìṣun ìṣàlẹ̀.

16. Àwọn ìran Kénì tí wọ́n jẹ́ àna Móṣè bá àwọn Júdà gòkè ní gúṣù nítorí Árádì àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì sì jùmọ̀ ń gbé pọ̀ láti ìgbà náà.

17. Ó sì ṣe, àwọn ológun Júdà tẹ̀lé àwọn ológun Ṣíméónì arákùnrin wọn, wọ́n sì lọ bá àwọn ará Kénánì tí ń gbé Ṣéfátì jagun, wọ́n sì run ìlú náà pátapáta, ní báyìí à ò pe ìlú náà ní Hómà (Hómà èyí tí ń jẹ́ ìparun).

18. Àwọn ogun Júdà sì ṣẹ́gun Gásà àti àwọn agbègbè rẹ̀, Ásíkélénì àti Ékírónì pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó yí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ká.

19. Olúwa sì wà pẹ̀lú ẹ̀yà Júdà, wọ́n gba ilẹ̀ òkè ṣùgbọ́n wọn kò le lé àwọn ènìyàn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí wọ́n ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin.

20. Gẹ́gẹ́ bí Móṣè ti ṣèlérí, wọ́n fún Kélẹ́bù ní Hébírónì ó sì lé àwọn tí ń gbé ibẹ̀ kúrò; àwọn náà ni ìran àwọn ọmọ Ánákì mẹ́ta.

21. Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni wọn kò le lé àwọn Jébúsì tí wọ́n ń gbé Jérúsálẹ́mù nítorí náà wọ́n ń gbé àárin àwọn Ísírẹ́lì títí di òní.

22. Àwọn ẹ̀yà Jóṣẹ́fù sì bá Bẹ́tẹ́lì jagun, Olúwa ṣíwájú pẹ̀lú wọn.

23. Nígbà tí ẹ̀yà Jóṣẹ́fù rán àwọn ènìyàn láti lọ yọ́ Bẹ́tẹ́lì wò (orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí ni Lúsì).

24. Àwọn ayọ́lẹ̀wò náà rí ọkùnrin kan tí ń jáde láti inú ìlú náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ọ̀nà àti wọ ìlú yìí hàn wá, àwa ó sì dá ẹ̀mìí rẹ sí, a ó sì ṣe àánú fún ọ.”

25. Ó sì fi ọ̀nà ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n dá ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ si.

26. Ọkùnrin náà sí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hítì, ó sì tẹ ìlú kan dó, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Lúsì èyí sì ni orúkọ rẹ̀ títí di òní.

27. Àwọn ẹ̀yà Mánásè sì kùnà láti lé àwọn tí ń gbé Bẹti-Sésínì àti àwọn ìlú agbègbè wọn jáde, tàbí àwọn ará Tánákì àti àwọn ìgbéríko rẹ̀, tàbí àwọn olùgbé Mégídò àti àwọn ìgbéríko tí ó yí i ká torí pé àwọn ará Kénánì ti pinnu láti máa gbé ìlú náà.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 1