Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ọbadáyà 1:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìran ti Ọbadáyà. Èyí ni Olúwa Ọlọ́run wí nípa Édómù.Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá:A sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo aláìkọlà láti sọ pé,“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.”

2. “Kíyèsí i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrin àwọn aláìkọlà;ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọpọ̀,

3. Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ,ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta,tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga,ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé,‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’

4. Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì,Bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárin àwọn ìràwọ̀,Láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,”ni Olúwa wí.

5. “Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá,Bí àwọn ọlọ́sà ní òru,Áà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́:ṣé wọn kò jalè tó bí wọ́n ti fẹ́?Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá,ṣé wọn kò ni fi èésẹ́ èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀?

6. Báwo ni a ṣe se àwárí nǹkan Ísọ̀tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde

7. Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ:Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ;àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́,ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.”

8. Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà,Èmi yóò pa àwọn ọlọ́gbọ́n Édómù run,àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Ísọ̀?

9. A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, Ìwọ Témánì,gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Ísọ̀ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.

Ka pipe ipin Ọbadáyà 1