Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 24:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nísinsìnyìí nígbà tí Bálámù rí i wí pé ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn láti bùkún àwọn Ísírẹ́lì, kò lo ọ̀nà ìṣoṣó gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ó yí ojú rẹ̀ sí apá ihà.

2. Nígbà tí Bálámù wo ìta ó sì rí Ísírẹ́lì tí wọ́n pàgọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà sórí rẹ̀

3. ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀:“Ó wí pé Bálámù ọmọ Béórì,òwe ẹni tí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀,

4. Òwe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè,ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì là:

5. “Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ Jákọ́bù,àti ibùgbé rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì!

6. “Gẹ́gẹ́ bí àfonífojì tí ó tàn jáde,gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá,gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn,gẹ́gẹ́ bí igi òpépé tí ó wà lẹ́bá odò.

7. Omi yóò sàn láti inú garawa:èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.“Ọba wọn yóò ga ju Ágágì lọ;ìjọba wọn yóò di gbígbéga.

8. “Ọlọ́run mú wọn jáde láti Éjíbítì wá;wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.Wọ́n jẹ orílẹ̀ èdè run,wọ́n fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́;wọ́n fi idà wọn gún wọn.

9. Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún,bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn?“Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ,kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!”

10. Nígbà náà ni ìbínú Bálákì sì dé sí Bálámù. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀ta mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí.

11. Nísinsìnyìí kúrò lọ́dọ̀ mi kíákíá kí o sì máa relé! Mo sọ wí pé màá sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n Olúwa kò jẹ́ kí o gba èrè yìí.”

12. Bálámù dá Bálákì lóhùn, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí o rán sí mi wí pé,

13. ‘Kó dà bí Bálákì bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, n kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa: ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ’?

14. Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 24