Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 14:35-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Èmi, Olúwa, lo sọ bẹ́ẹ̀; Èmi ó sì ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí ìjọ ènìyàn búburú yìí tí wọ́n kóra wọn jọ lòdì sí mi. Nínú ihà yìí ni òpin yóò dé bá wọn, ibẹ̀ ni wọn yóò kú sí.”

36. Àwọn ọkùnrin tí Mósè rán láti yẹ ilẹ̀ wò, tí wọ́n sì mú àwọn ènìyàn kùn sí i nípa ìròyìn búburú tí wọ́n mú wá nípa ilẹ̀ náà;

37. Olúwa sì kọlu àwọn ọkùnrin tó mú ìròyìn búburú wá nípa ilẹ̀ náà, àjàkálẹ̀-àrùn sì pa wọ́n níwájú Olúwa.

38. Nínú gbogbo àwọn tó lọ yẹ ilẹ̀ náà wò, Jóṣúà ọmọ Núnì àti Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ló yè é.

39. Nígbà tí Mósè sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì sunkún gidigdidi.

40. Wọ́n dìde ní àárọ̀ ọjọ́ kejì wọ́n sì gòkè lọ sí ìlú orí òkè, wọ́n wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀, Àwa yóò lọ síbi tí Olúwa ṣèlérí fún wa.”

41. Mósè sì dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ṣẹ̀ sí òfin Olúwa? Èyí kò le yọrí sí rere!

42. Ẹ má ṣe gòkè lọ nítorí pé Olúwa kò sí láàrin yín. Ki á má baà lù yín bolẹ̀ níwájú àwọn ọ̀ta yín.

43. Nítorí pé àwọn ará Ámélékì àti àwọn ará Kénánì yóò kojú yín níbẹ̀. Nítorí pé Ẹ ti yà kúrò ní ọ̀nà Olúwa, Olúwa kò sì ní í wà pẹ̀lú yín.”

44. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, pẹ̀lú àìfarabalẹ̀ wọn, wọ́n gòkè lọ sórí òkè náà, láì jẹ́ pé àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa tàbí Mósè kúrò nínú ibùdó.

45. Àwọn ará Ámálékì àti àwọn ará Kénánì tó ń gbé lórí òkè sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n, wọ́n bá wọn jà, wọ́n sì lé wọn títí dé Hómà.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 14