Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 14:24-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ṣùgbọ́n nítorí pé Kélẹ́bù ìránṣẹ́ mi ní ẹ̀mi ọ̀tọ̀, tí ó sì tún tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, èmi ó mu dé ilẹ̀ náà tó lọ yẹ̀ wò, irú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì jogún rẹ̀.

25. Níwọ̀n ìgbà tí àwọn ará Ámálékì àti àwọn ará Kénánì ń gbé ní àfonífojì, ẹ yípadà lọ́la kí ẹ sì dojú kọ ihà lọ́nà Òkun Pupa.”

26. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé:

27. “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ìjọ ènìyàn búburú yìí yóò fi máa kùn sími? Mo ti gbọ́ kíkùn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kùn sí mi.

28. Sọ fún wọn, Bí Mo ti wà láàyè nítòótọ́ ni Olúwa wí, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ wí létí mi ni èmi ó ṣe fún un yín.

29. Nínú ihà yìí ni ẹ ó kú sí, gbogbo ẹ̀yín tí ẹ kùn láti ọmọ ogún ọdún ó lé àní gbogbo ẹ̀yin tí a kà.

30. Ọ̀kan nínú yín kò ní í dé ilẹ̀ tí mo búra láti fi ṣe ilẹ̀ yín, àyàfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè àti Jósúà ọmọ Núnì.

31. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ yín tí ẹ wí pé wọn ó di ìjẹ, àwọn ni n ó mú dé bẹ̀ láti gbádùn ilẹ̀ tí ẹ kọ̀ sílẹ̀.

32. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, òkú yín yóò ṣubú ní ihà yìí.

33. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín yóò sì máa rin kiri nínú ihà fun ogójì ọdún (40) wọn ó máa jìyà nítorí àìnígbàgbọ́ yín, títí tí ọkàn gbogbo yín yóò fi ṣòfò tán ní ihà.

34. Fún ogójì ọdún èyí jẹ́ ọdún kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ogójì ọjọ́ tí ẹ fi yẹ ilẹ̀ náà wò ẹ̀yin ó sì jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì mọ bí ó ti rí láti lòdì sí mi.

35. Èmi, Olúwa, lo sọ bẹ́ẹ̀; Èmi ó sì ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí ìjọ ènìyàn búburú yìí tí wọ́n kóra wọn jọ lòdì sí mi. Nínú ihà yìí ni òpin yóò dé bá wọn, ibẹ̀ ni wọn yóò kú sí.”

36. Àwọn ọkùnrin tí Mósè rán láti yẹ ilẹ̀ wò, tí wọ́n sì mú àwọn ènìyàn kùn sí i nípa ìròyìn búburú tí wọ́n mú wá nípa ilẹ̀ náà;

37. Olúwa sì kọlu àwọn ọkùnrin tó mú ìròyìn búburú wá nípa ilẹ̀ náà, àjàkálẹ̀-àrùn sì pa wọ́n níwájú Olúwa.

38. Nínú gbogbo àwọn tó lọ yẹ ilẹ̀ náà wò, Jóṣúà ọmọ Núnì àti Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ló yè é.

39. Nígbà tí Mósè sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì sunkún gidigdidi.

40. Wọ́n dìde ní àárọ̀ ọjọ́ kejì wọ́n sì gòkè lọ sí ìlú orí òkè, wọ́n wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀, Àwa yóò lọ síbi tí Olúwa ṣèlérí fún wa.”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 14