Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 14:12-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Èmi ó kọlù wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn, èmi ó gba ogún wọn lọ́wọ́ wọn, èmi ó sì pa wọ́n run ṣùgbọ́n èmi ó sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá tó sì lágbára jù wọ́n lọ.”

13. Ṣùgbọ́n Mósè sọ fún Olúwa pé, “Nígbà náà ni àwọn ará Éjíbítì yóò gbọ́; Nítorí pé nípa agbára Írẹ ni ìwọ fi mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí jáde kúrò láàrin wọn.

14. Wọ́n ó sì sọ fún àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí. Àwọn tó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ìwọ Olúwa wà láàrin àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti pé wọ́n rí ìwọ, Olúwa, ní ojúkojú, àti pé ìkùukùu àwọsánmọ̀ rẹ dúró lórí wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ń lọ níwájú wọn pẹ̀lú ìkùukùu àwọsánmọ̀ ní ọ̀sán àti pẹ̀lú ọ̀wọ́n iná ní òru.

15. Bí ìwọ bá pa àwọn ènìyàn wọ̀nyí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀ èdè tó bá gbọ́ ìròyìn yìí nípa rẹ yóò wí pé.

16. ‘Nítorí pé Olúwa kò le è mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí dé ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún wọn; torí èyí ló ṣe pa wọ́n sínú ihà yìí.’

17. “Báyìí, mo gbàdúrà, jẹ́ kí agbára Olúwa tóbi gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣọ pé:

18. ‘Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ tó dúró sinsin, tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá jìn. Bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà; tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta àti ìran kẹrin.’

19. Dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn yìí jìn wọ́n, mo bẹ̀ ọ́, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ, bí o ti ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jìn wọ́n láti ìgbà tí o ti kó wọn kúrò ní Éjíbítì di ìsin yìí.”

20. Olúwa sì dáhùn pé: “Mo ti dárí jìn wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ;

21. Ṣùgbọ́n nítòótọ́ bí mo ti wà láàyè, gbogbo ayé yóò kún fún ògo Olúwa.

22. Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tó rí òg mi àti wọn iṣẹ́ àmì ìyanu tí mo ṣe ní ilẹ̀ Éjíbítì àti nínú ihà ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí mi, tí wọn sì dán mi wò ní ìgbà mẹ́wàá yìí,

23. Ọ̀kan nínú wọn kò níi rí ilẹ̀ náà tí mo ṣe ìlérí ní ìbúra láti fún baba ńlá wọn. Kò sí ọ̀kan nínú àwọn tó kẹ́gàn mi tí yóò rí ilẹ̀ náà.

24. Ṣùgbọ́n nítorí pé Kélẹ́bù ìránṣẹ́ mi ní ẹ̀mi ọ̀tọ̀, tí ó sì tún tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, èmi ó mu dé ilẹ̀ náà tó lọ yẹ̀ wò, irú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì jogún rẹ̀.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 14