Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 1:43-54 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

43. Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Náfítalì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n-ó-lé-egbéje (53,400).

44. Wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí Mósè àti Árónì kà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí méjìlá (12) fún Ísírẹ́lì, tí ẹnìkọ̀ọ̀kan sojú fún ìdílé rẹ̀.

45. Gbogbo ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún (20) sókè, tó sì lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

46. Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́-ó-lé-egbéjìdínlógún-dín-àádọ́ta, (603,550).

47. A kò ka àwọn ìdílé ẹ̀yà Léfì mọ́ àwọn ìyókù.

48. Nítorí Olúwa ti sọ fún Mósè pé,

49. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ka ẹ̀yà Léfì, tàbí kí o kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì:

50. Dípò èyí yan àwọn ọmọ Léfì láti jẹ́ alábojútó àgọ́. Ẹrí, lórí gbogbo ohun èlò àti ohun gbogbo tó jẹ́ ti àgọ́ ẹ̀rí. Àwọn ni yóò máa gbé àgọ́ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, wọn ó máa mójú tó o, kí wọn ó sì máa pàgọ́ yí i ká.

51. Ìgbàkígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀ṣíwájú, àwọn ọmọ Léfì ni yóò tu palẹ̀, nígbàkígbà tí a bá sì tún pa àgọ́, àwọn ọmọ Léfì náà ni yóò ṣe é. Ẹnikẹ́ni tó bá súnmọ́ tòsí ibẹ̀, pípa ni kí ẹ pa á

52. kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa àgọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn olúkúlùkù ní ibùdó tirẹ̀ lábẹ́ ọ̀págun tirẹ̀.

53. Àwọn ọmọ Léfì yóò jẹ́ alábojútó àti olùtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà, kí ìbínú má ba à sí lára ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; kí àwọn ọmọ Léfì sì máa ṣe ìtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà.”

54. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 1