Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 10:16-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Àdóníjà, Bígífáyì, Ádínì,

17. Átérì, Heṣekáyà, Áṣúrì,

18. Hódáyà, Háṣámù, Béṣáyì,

19. Hárífì, Ánátótì, Nébáyì,

20. Mágípíásì, Mésúlámù, Héṣírì

21. Méṣésábélì, Ṣádókù, Jádúyà

22. Pélátíyà, Hánánì, Hánáyà,

23. Hóséà, Hananáyà, Háṣúbù,

24. Hálóésì, Píléhà, Ṣóbékì,

25. Réhúmù, Háṣábínà, Mááséyà,

26. Áhíyà, Hánánì, Ánánì,

27. Málúkù, Hárímù, àti Báánà.

28. “Àwọn ènìyàn tó kù—àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn aṣọ́nà, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn àjèjì nítorí òfin Ọlọ́run, papọ̀ pẹ̀lú ìyàwóo wọn, gbogbo ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, tí òye yé

29. gbogbo wọn fi ara mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọlọ́lá, wọ́n sì fi ègún àti ìbúra dé ara wọn láti máa tẹ̀lé òfin Ọlọ́run tí a fi fún wọn ní ipasẹ̀ Móṣè ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti láti pa gbogbo àṣẹ, ìlànà àti òfín Olúwa, wa mọ́ dáadáa.

30. “A ti ṣe ìlérí pé, a kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn tí wọ́n wà ní àyíkáa wa bí ìyàwó, tàbí fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa.

31. “Nígbà tí àwọn ènìyàn àdúgbò bá mú ọjà tàbí oúnjẹ (ọkà) wá ní ọjọ́ ìsimi láti tà, àwa kò ní ràá ní ọwọ́ọ wọn ní ọjọ́ ìsimi tàbí ní ọjọ́ mímọ́ kankan. Ní gbogbo ọdún keje àwa kò ní ro ilẹ̀ náà, a ó sì pa gbogbo àwọn gbèsè rẹ́.

32. “Àwa gbà ojúṣe láti máa pa àṣẹ mọ́ pé a ó máa san ìdámẹ́ta ṣékélì ní ọdọọdún fún iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa:

33. Nítorí oúnjẹ tí ó wà lóríi tábìlì; nítorí ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun ṣíṣun ìgbà gbogbo; nítorí ọrẹ ọjọ́ ìsimi, ti àyájọ́ oṣù tuntun àti àṣè tí a yàn; nítorí ọrẹ mímọ́; nítorí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì; àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.

34. “Àwa, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti àwọn ènìyàn náà ti dìbò láti pinnu ìgbà tí olúkúlùkù àwọn ìdílé yóò mú ọrẹ igi wá láti ṣun lọ́ríi pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa sí ilé Ọlọ́run wa, ní àkókò tí a yàn ní ọdọọdún. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin.

35. “Àwa tún gbà ojuṣe láti mú àkọ́so àwọn èso wa wá àti gbogbo èso igi wá ní ilé Olúwa.

Ka pipe ipin Nehemáyà 10